4 Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, gbogbo ìjọ, ati àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà gbà wọ́n tọwọ́-tẹsẹ̀. Wọ́n wá ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọrun ti ṣe fún wọ́n.
5 Àwọn kan láti inú ẹgbẹ́ àwọn Farisi tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ wá dìde. Wọ́n ní, “Dandan ni pé kí á kọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí ó bá fẹ́ di onigbagbọ nílà, kí á sì pàṣẹ fún wọn láti máa pa Òfin Mose mọ́.”
6 Gbogbo àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà bá péjọ láti rí sí ọ̀rọ̀ yìí.
7 Àríyànjiyàn pupọ ni ó bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Peteru bá dìde, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ̀yin gan-an mọ̀ pé ní àtijọ́ Ọlọrun yàn mí láàrin yín pé láti ẹnu mi ni àwọn tí kì í ṣe Juu yóo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere, kí wọ́n lè gba Jesu gbọ́.
8 Ọlọrun olùmọ̀ràn ọkàn fún wọn ní ìwé ẹ̀rí nígbà tí ó fún wọn ní Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti fún wa.
9 Kò fi ìyàtọ̀ kankan sáàrin àwa ati àwọn; ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nítorí wọ́n gba Jesu gbọ́.
10 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ní ṣe tí ẹ fi fẹ́ dán Ọlọrun wò, tí ẹ fẹ́ gbé àjàgà tí àwọn baba wa ati àwa náà kò tó rù, rù àwọn ọmọ-ẹ̀yìn?