29 Ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá bèèrè iná, ó pa kuuru wọ inú iyàrá, ó ń gbọ̀n láti orí dé ẹsẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Paulu ati Sila.
30 Ó mú wọn jáde, ó ní, “Ẹ̀yin alàgbà, kí ni ó yẹ kí n ṣe kí n lè là?”
31 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Gba Jesu Oluwa gbọ́, ìwọ ati ìdílé rẹ yóo sì là.”
32 Wọ́n bá sọ ọ̀rọ̀ Oluwa fún òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀.
33 Ní òru náà, ó mú wọn, ó wẹ ọgbẹ́ wọn. Lójú kan náà òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì ṣe ìrìbọmi.
34 Ó bá mú wọn wọ ilé, ó fún wọn ní oúnjẹ. Inú òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn pupọ nítorí ó ti gba Ọlọrun gbọ́.
35 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn adájọ́ rán àwọn iranṣẹ sí ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n pé, kí ó dá àwọn eniyan náà sílẹ̀.