6 Wọ́n gba ilẹ̀ Firigia ati Galatia kọjá. Ẹ̀mí Mímọ́ kò gbà wọ́n láàyè láti lọ waasu ọ̀rọ̀ Oluwa ní Esia.
7 Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia. Ṣugbọn Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn.
8 Nígbà tí wọ́n ti la Misia kọjá, wọ́n dé Tiroasi.
9 Nígbà tí ó di alẹ́, Paulu rí ìran kan. Ó rí ọkunrin kan ará Masedonia tí ó dúró, tí ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Sọdá sí Masedonia níbí kí o wá ràn wá lọ́wọ́.”
10 Gbàrà tí ó rí ìran náà, a wá ọ̀nà láti lọ sí Masedonia; a pinnu pé Ọlọrun ni ó pè wá láti lọ waasu fún wọn níbẹ̀.
11 Nígbà tí a wọ ọkọ̀ láti Tiroasi, a lọ tààrà sí Samotirake. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Neapoli.
12 Láti ibẹ̀, a lọ sí Filipi tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ Masedonia. Àwọn ará Romu ni wọ́n tẹ ìlú yìí dó. A bá wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan.