10 Nítorí n óo wà pẹlu rẹ. Kò sí ẹni tí yóo fọwọ́ kàn ọ́ láti ṣe ọ́ níbi. Nítorí mo ní eniyan pupọ ninu ìlú yìí.”
11 Paulu gbé ààrin wọn fún ọdún kan ati oṣù mẹfa, ó ń kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
12 Ṣugbọn nígbà tí Galio di gomina Akaya, àwọn Juu fi ohùn ṣọ̀kan láti dìde sí Paulu. Wọ́n bá mú un lọ sí kóòtù níwájú Galio.
13 Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń kọ́ àwọn eniyan láti sin Ọlọrun ní ọ̀nà tí ó lòdì sí òfin.”
14 Bí Paulu ti fẹ́ lanu láti fèsì, Galio sọ fún àwọn Juu pé, “Ẹ̀yin Juu, bí ó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kan tabi ọ̀ràn burúkú kan ni ẹ mú wá, ǹ bá gbọ́ ohun tí ẹ ní sọ;
15 ṣugbọn tí ó bá jẹ́ àríyànjiyàn nípa àwọn ọ̀rọ̀ tabi orúkọ, tabi òfin yín, ẹ lọ rí sí i fúnra yín. N kò fẹ́ dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.”
16 Ni ó bá lé wọn kúrò ní kóòtù.