18 Àní, ní àkókò náà, n óo tú Ẹ̀mí misórí àwọn ẹrukunrin miati sí orí àwọn ẹrubinrin mi,àwọn náà yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.
19 N óo fi ohun ìyanu hàn lókè ọ̀run,ati ohun abàmì lórí ilẹ̀ ayé;ẹ̀jẹ̀, ati iná, ìkùukùu ati èéfín.
20 Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo di ẹ̀jẹ̀,kí ó tó di ọjọ́ ńlá tí ó lókìkí, ọjọ́ Oluwa.
21 Ní ọjọ́ náà gbogbo ẹni tí óbá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” ’
22 “Ẹ̀yin ará, ọmọ Israẹli, ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Jesu ará Nasarẹti ni ẹni tí Ọlọrun ti fihàn fun yín pẹlu iṣẹ́ agbára, iṣẹ́ ìyanu, iṣẹ́ abàmì tí Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín. Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.
23 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun ati ètò tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, a fi í le yín lọ́wọ́, ẹ jẹ́ kí àwọn aláìbìkítà fún Òfin kàn án mọ́ agbelebu, ẹ sì pa á.
24 Ṣugbọn Ọlọrun tú ìdè ikú, ó jí i dìde ninu òkú! Kò jẹ́ kí ikú ní agbára lórí rẹ̀.