26 Nítorí náà inú mi dùn, mo bú sẹ́rìn-ín.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan ẹlẹ́ran-ara ni mí,sibẹ n óo gbé ìgbé-ayé mi pẹlu ìrètí;
27 nítorí o kò ní fi ọkàn mi sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú;bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.
28 O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí,O óo sì fi ayọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.’
29 “Ẹ̀yin ará, mo sọ fun yín láìṣe àní-àní pé Dafidi baba-ńlá wa kú, a sì sin ín; ibojì rẹ̀ wà níhìn-ín títí di òní.
30 Ṣugbọn nítorí ó jẹ́ aríran, ó sì mọ̀ pé Ọlọrun ti búra fún òun pé ọ̀kan ninu ọmọ tí òun óo bí ni yóo jókòó lórí ìtẹ́ òun,
31 ó ti rí i tẹ́lẹ̀ pé Mesaya yóo jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí nìyí tí ó fi sọ pé,‘A kò fi í sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú;bẹ́ẹ̀ ni ẹran-ara rẹ̀ kò díbàjẹ́.’
32 Jesu yìí ni Ọlọrun jí dìde. Gbogbo àwa yìí sì ni ẹlẹ́rìí.