26 Ó ní,‘Lọ sọ fún àwọn eniyan yìí pé:Ẹ óo fetí yín gbọ́, ṣugbọn kò ní ye yín;Ẹ óo wò ó títí, ṣugbọn ẹ kò ní mọ̀ ọ́n.
27 Nítorí ọkàn àwọn eniyan yìí kò ṣí; wọ́n ti di alágbọ̀ọ́ya,wọ́n ti dijú.Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀,wọn ìbá fi ojú wọn ríran,wọn ìbá fetí gbọ́ràn,òye ìbá yé wọn,wọn ìbá yipada;èmi ìbá sì wò wọ́n sàn.’
28 “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé a ti rán iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọrun yìí sí àwọn tí kì í ṣe Juu. Àwọn ní tiwọn yóo gbọ́.”
29 Nígbà tí Paulu ti sọ báyìí tán, àwọn Juu túká, wọ́n ń bá ara wọn jiyàn kíkankíkan.
30 Fún ọdún meji gbáko ni Paulu fi gbé ninu ilé tí ó gbà fúnra rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ń gba gbogbo àwọn tí ó ń wá rí i.
31 Ó ń waasu ìjọba Ọlọrun. Ó ń kọ́ àwọn eniyan nípa Oluwa Jesu Kristi láì bẹ̀rù ohunkohun. Ẹnikẹ́ni kò sì dí i lọ́wọ́.