18 Wọ́n bá mú àwọn aposteli, wọ́n tì wọ́n mọ́lé ninu ilé ẹ̀wọ̀n ìgboro ìlú.
19 Nígbà tí ó di òru, angẹli Oluwa ṣí ìlẹ̀kùn ilé-ẹ̀wọ̀n, ó sìn wọ́n jáde, ó sọ fún wọn pé,
20 “Ẹ lọ dúró ninu Tẹmpili kí ẹ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyè yìí fún àwọn eniyan.”
21 Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n wọ inú Tẹmpili lọ nígbà tí ojúmọ́ mọ́, wọ́n bá ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.Nígbà tí Olórí Alufaa dé pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó pe ìgbìmọ̀ ati gbogbo àwọn àgbààgbà láàrin àwọn ọmọ Israẹli jọ. Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí inú ẹ̀wọ̀n kí wọn lọ mú àwọn aposteli náà wá.
22 Nígbà tí àwọn tí wọ́n rán dé ilé-ẹ̀wọ̀n, wọn kò rí wọn níbẹ̀. Wọ́n bá pada lọ jíṣẹ́ pé,
23 “A fojú wa rí ilé-ẹ̀wọ̀n ní títì, a bá àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọ tí wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà. Ṣugbọn nígbà tí a ṣílẹ̀kùn, tí a wọ inú ilé, a kò rí ẹnìkan.”
24 Nígbà tí ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ ti Tẹmpili ati àwọn olórí alufaa gbọ́ ìròyìn yìí, ọkàn wọn dàrú; wọ́n ń ronú pé, irú kí ni eléyìí?