4 ó bá ṣubú lulẹ̀. Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó bi í pé, “Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?”
5 Saulu bèèrè pé, “Ta ni ọ́, Oluwa?”Ẹni náà bá dáhùn pé, “Èmi ni Jesu, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.
6 Dìde nisinsinyii, kí o wọ inú ìlú lọ. A óo sọ ohun tí o níláti ṣe fún ọ.”
7 Àwọn ọkunrin tí ó ń bá a rìn dúró. Wọn kò sọ ohunkohun. Wọ́n ń gbọ́ ohùn eniyan, ṣugbọn wọn kò rí ẹnìkankan.
8 Saulu bá dìde nílẹ̀, ó la ojú sílẹ̀ ṣugbọn kò ríran. Wọ́n bá fà á lọ́wọ́ lọ sí Damasku.
9 Fún ọjọ́ mẹta, kò ríran, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu.
10 Ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan wà ní Damasku tí ń jẹ́ Anania. Oluwa pè é ní ojú ìran, ó ní, “Anania!”Anania bá dáhùn pé, “Èmi nìyí, Oluwa.”