13 Ní ààrin àwọn ọ̀pá fìtílà yìí ni ẹnìkan wà tí ó dàbí eniyan. Ó wọ ẹ̀wù tí ó balẹ̀ dé ilẹ̀. Ó fi ọ̀já wúrà gba àyà.
14 Irun orí rẹ̀ funfun gbòò bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ojú rẹ̀ ń kọ yànràn bí iná.
15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí idẹ tí ń dán, tí alágbẹ̀dẹ ń dà ninu iná. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi òkun.
16 Ó mú ìràwọ̀ meje lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Idà olójú meji tí ó mú yọ jáde lẹ́nu rẹ̀. Ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ bí oòrùn ọ̀sán gangan.
17 Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó bá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi. Ó ní, “Má bẹ̀rù. Èmi ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn.
18 Èmi ni ẹni tí ó wà láàyè. Mo kú, ṣugbọn mo ti jí, mo sì wà láàyè lae ati laelae. Àwọn kọ́kọ́rọ́ ikú ati ti ipò òkú wà lọ́wọ́ mi.
19 Nítorí náà kọ àwọn ohun tí o rí sílẹ̀, ati àwọn ohun tí ó wà nisinsinyii ati àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la.