12 Wọ́n wá gbọ́ ohùn líle láti ọ̀run wá tí ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá síhìn-ín.” Ni wọ́n bá gòkè lọ sọ́run ninu ìkùukùu, lójú àwọn ọ̀tá wọn.
13 Ilẹ̀ mì tìtì, ìdámẹ́wàá ìlú bá wó. Ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan ni ó kú nígbà tí ilẹ̀ náà mì. Ẹ̀rù ba àwọn tí ó kù, wọ́n sì fi ògo fún Ọlọrun ọ̀run.
14 Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú keji kọjá. Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kẹta fẹ́rẹ̀ dé.
15 Angẹli keje fun kàkàkí rẹ̀, àwọn ohùn líle kan ní ọ̀run bá sọ pé, “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀. Yóo jọba lae ati laelae.”
16 Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ wọn níwájú Ọlọrun bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun.
17 Wọ́n ní,“A fi ìyìn fún ọ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare,ẹni tí ó wà, tí ó ti wà,nítorí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ń jọba.
18 Inú àwọn orílẹ̀-èdè ru,ṣugbọn àkókò ibinu rẹ dé,ó tó àkókò láti ṣe ìdájọ́ àwọn òkú,ati láti fi èrè fún àwọn iranṣẹ rẹ, àwọn wolii, àwọn eniyan rẹ,ati àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ, ìbáà ṣe àwọn mẹ̀kúnnù tabi àwọn eniyan ńláńlá.Àkókò dé láti pa àwọn tí ó ń ba ayé jẹ́ run.”