7 Ogun wá bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run. Mikaeli ati àwọn angẹli rẹ̀ ń bá Ẹranko Ewèlè náà jà. Ẹranko Ewèlè yìí ati àwọn angẹli rẹ̀ náà jà títí,
8 ṣugbọn kò lágbára tó láti ṣẹgun. Wọ́n bá lé òun ati àwọn angẹli rẹ̀ kúrò ní ọ̀run.
9 Wọ́n lé Ẹranko Ewèlè náà jáde–ejò àtijọ́ nì tí à ń pè ní Èṣù, tabi Satani tí ó ń tan àwọn tí ó ń gbé inú ayé jẹ. Wọ́n lé e jáde lọ sinu ayé, ati òun ati àwọn angẹli rẹ̀.
10 Mo wá gbọ́ ohùn líle kan ní ọ̀run tí ó sọ pé, “Àkókò ìgbàlà nìyí ati ti agbára, ati ìjọba ti Ọlọrun wa, ati àkókò àṣẹ Kristi rẹ̀. Nítorí a ti lé Olùfisùn àwọn onigbagbọ ara wa jáde, tí ó ń fi ẹjọ́ wọn sùn níwájú Ọlọrun wa tọ̀sán-tòru.
11 Wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan ati ẹ̀rí ọ̀rọ̀ tí wọ́n jẹ́ ṣẹgun rẹ̀. Nítorí wọn kò ka ẹ̀mí wọn sí pé ó ṣe iyebíye jù kí wọ́n kú lọ.
12 Nítorí náà, ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé inú wọn. Ó ṣe fun yín, ayé, ati fún òkun! Nítorí Èṣù ti dé sáàrin yín. Inú rẹ̀ ń ru, nítorí ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ni ó kù fún òun.”
13 Nígbà tí Ẹranko Ewèlè náà rí i pé a lé òun jáde sinu ayé, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé obinrin tí ó bí ọmọkunrin nnì kiri.