10 Bí ẹnikẹ́ni bá níláti lọ sí ìgbèkùn, yóo lọ sí ìgbèkùn. Bí ẹnikẹ́ni bá fi idà pa eniyan, idà ni a óo fi pa òun náà. Níhìn-ín ni ìfaradà ati ìdúró ṣinṣin àwọn eniyan Ọlọrun yóo ti hàn.
11 Mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó jáde láti inú ilẹ̀. Ó ní ìwo meji bíi ti Ọ̀dọ́ Aguntan. Ó ń sọ̀rọ̀ bíi ti Ẹranko Ewèlè.
12 Ó ń lo àṣẹ bíi ti ẹranko àkọ́kọ́, lójú ẹranko àkọ́kọ́ fúnrarẹ̀. Ó mú kí ayé ati àwọn tí ó ń gbé inú rẹ̀ júbà ẹranko àkọ́kọ́, tí ọgbẹ́ rẹ̀ ti san.
13 Ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì ńláńlá. Ó mú kí iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sí ayé lójú àwọn eniyan.
14 Ó fi iṣẹ́ abàmì tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà tan àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n yá ère ẹranko tí a ti fi idà ṣá lọ́gbẹ́ tí ó tún yè.
15 A fún un ní agbára láti fi èémí sinu ère ẹranko náà, kí ère ẹranko náà lè fọhùn, kí ó lè pa àwọn tí kò bá júbà ère ẹranko náà.
16 Lẹ́yìn náà, gbogbo eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan ńláńlá ati ọlọ́rọ̀ ati talaka, ati ẹrú ati òmìnira ni ẹranko yìí mú kí wọ́n ṣe àmì sí ọwọ́ ọ̀tún tabi iwájú wọn.