Ìfihàn 17:5-11 BM

5 Orúkọ àṣírí kan wà níwájú rẹ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ ni: “Babiloni ìlú ńlá, ìyá àwọn àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin ayé.”

6 Mo wá rí obinrin náà tí ó ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun ní àmuyó, pẹlu ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu.Ìyanu ńlá ni ó jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí obinrin náà.

7 Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni ó yà ọ́ lẹ́nu? N óo sọ àṣírí obinrin náà fún ọ ati ti ẹranko tí ó gùn, tí ó ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá.

8 Ẹranko tí o rí yìí ti wà láàyè nígbà kan rí, ṣugbọn kò sí láàyè mọ́ nisinsinyii. Ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò, tí yóo gòkè wá láti inú ọ̀gbun jíjìn, tí yóo wá lọ sí ibi ègbé. Nígbà tí wọ́n bá rí ẹranko náà ẹnu yóo ya àwọn tí ó ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, nítorí ó ti wà láàyè, ṣugbọn kò sí láàyè nisinsinyii, ṣugbọn yóo tún pada yè.

9 “Ọ̀rọ̀ yìí gba ọgbọ́n. Orí meje tí ẹranko náà ní jẹ́ òkè meje tí obinrin náà jókòó lé lórí. Wọ́n tún jẹ́ ọba meje.

10 Marun-un ninu wọn ti kú. Ọ̀kan wà lórí oyè nisinsinyii. Ọ̀kan yòókù kò ì tíì jẹ. Nígbà tí ó bá jọba, àkókò díẹ̀ ni yóo ṣe lórí oyè.

11 Ẹranko tí ó ti wà láàyè rí, tí kò sí mọ́, ni ẹkẹjọ, ṣugbọn ó wà ninu àwọn meje tí ń lọ sinu ègbé.