14 Mo bá dá a lóhùn pé, “Alàgbà, ìwọ ni ó mọ̀ wọ́n.”Ó wá sọ fún mi pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ti kọjá ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan.
15 Nítorí èyí ni wọ́n ṣe wà níwájú ìtẹ́ Ọlọrun, tí wọn ń júbà tọ̀sán-tòru ninu Tẹmpili rẹ̀. Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà yóo máa bá wọn gbé.
16 Ebi kò ní pa wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kò ní gbẹ wọ́n mọ́. Oòrùn kò ní pa wọ́n mọ́, ooru kankan kò sì ní mú wọn mọ́.
17 Nítorí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó wà láàrin ìtẹ́ náà ni yóo máa ṣe olùtọ́jú wọn, yóo máa dà wọ́n lọ síbi ìsun omi ìyè.Ọlọrun yóo wá nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.”