Ìfihàn 7:4-13 BM

4 Mo gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sí níwájú, wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ meje eniyan ó lé ẹgbaaji (144,000) láti inú gbogbo ẹ̀yà ọmọ Israẹli:

5-8 Láti inú ẹ̀yà Juda ẹgbaafa (12,000) ni a fi èdìdì sí níwájú, láti inú ẹ̀yà Reubẹni, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Gadi, ẹgbaafa (12,000); láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Nafutali, ẹgbaafa (12,000) láti inú ẹ̀yà Manase, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Simeoni, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Lefi, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Isakari, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Sebuluni ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Josẹfu, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ẹgbaafa (12,000).

9 Lẹ́yìn náà, mo rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ẹnikẹ́ni kò lè kà láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà, ati oríṣìíríṣìí èdè, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan. Wọ́n wọ aṣọ funfun. Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ lọ́wọ́.

10 Wọ́n wá ń kígbe pé, “Ti Ọlọrun wa tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ati ti Ọ̀dọ́ Aguntan ni ìgbàlà.”

11 Gbogbo àwọn angẹli tí ó dúró yí ìtẹ́ náà ká, ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n júbà Ọlọrun.

12 Wọ́n ń wí pé, “Amin! Ìyìn, ògo, ọgbọ́n, ọpẹ́, ọlá, agbára ati ipá ni fún Ọlọrun wa lae ati laelae. Amin!”

13 Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí bi mí pé, “Ta ni àwọn wọnyi tí a wọ̀ ní aṣọ funfun? Níbo ni wọ́n sì ti wá?”