Kọrinti Keji 11:20-26 BM

20 Bí ẹnìkan bá ń lò yín bí ẹrú, tí ó ń jẹ yín run, tí ó fi okùn mu yín, tí ó ń ṣe fùkẹ̀ láàrin yín, tí ó ń gba yín létí, ẹ ṣetán láti gba irú ẹni bẹ́ẹ̀.

21 Ojú tì mí láti gbà pé àwa kò lágbára tó láti hu irú ìwà bẹ́ẹ̀!Ṣugbọn bí ẹnìkan bá láyà láti fi ohun kan ṣe ìgbéraga, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ bí aṣiwèrè, èmi náà láyà láti ṣe ìgbéraga.

22 Ṣé Heberu ni wọ́n ni? Heberu ni èmi náà. Ọmọ Israẹli ni wọ́n? Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà. Ṣé ìdílé Abrahamu ni wọ́n? Òun ni èmi náà.

23 Iranṣẹ Kristi ni wọ́n? Tí n óo bá sọ̀rọ̀ bí ẹni tí orí rẹ̀ kò pé, mo jù wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Kristi. Mo ti fi agbára ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ. Mo ti wẹ̀wọ̀n nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Wọ́n ti nà mí nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Ẹ̀mí fẹ́rẹ̀ bọ́ lẹ́nu mi ní ọpọlọpọ ìgbà.

24 Ẹẹmarun-un ni àwọn Juu nà mí ní ẹgba mọkandinlogoji.

25 Ẹẹmẹta ni a fi ọ̀pá lù mí. A sọ mí lókùúta lẹ́ẹ̀kan. Ẹẹmẹta ni ọkọ̀ ojú omi tí mo wọ̀ rì. Fún odidi ọjọ́ kan, tọ̀sán-tòru, ni mo fi wà ninu agbami.

26 Ní ọpọlọpọ ìgbà ni mo wà lórí ìrìn àjò, tí mo wà ninu ewu omi, ewu lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, ewu láàrin àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ mi, ewu láàrin àwọn tíí ṣe Juu, ewu ninu ìlú, ewu ninu oko, ewu lójú òkun, ati ewu láàrin àwọn èké onigbagbọ.