4 A lè sọ èyí nítorí a ní igbẹkẹle ninu Ọlọrun nípa Kristi.
5 Kì í ṣe pé a ní agbára tó ninu ara wa, tabi pé a ti lè ṣe nǹkankan fúnra wa. Ṣugbọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti ní gbogbo nǹkan ní ànító.
6 Ọlọrun ni ó mú kí á lè jẹ́ iranṣẹ ti majẹmu titun, tí kì í ṣe ti òfin tí a kọ bíkòṣe ti Ẹ̀mí. Nítorí ikú ni òfin tí a kọ sílẹ̀ ń mú wá, ṣugbọn majẹmu ti Ẹ̀mí ń sọ eniyan di alààyè.
7 Bí òfin tí a kọ sí ara òkúta tí ó jẹ́ iranṣẹ ikú bá wá pẹlu ògo, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè ṣíjú wo Mose, nítorí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn ní ojú rẹ̀ fún àkókò díẹ̀,
8 báwo ni iranṣẹ ti Ẹ̀mí yóo ti lógo tó?
9 Bí iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa lẹ́bi bá lógo, báwo ni iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa láre yóo ti lógo tó?
10 Àní ohun tí ó lógo tẹ́lẹ̀ kò tún lógo mọ́ nítorí ohun mìíràn tí ògo tirẹ̀ ta á yọ.