7 Bí òfin tí a kọ sí ara òkúta tí ó jẹ́ iranṣẹ ikú bá wá pẹlu ògo, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè ṣíjú wo Mose, nítorí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn ní ojú rẹ̀ fún àkókò díẹ̀,
8 báwo ni iranṣẹ ti Ẹ̀mí yóo ti lógo tó?
9 Bí iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa lẹ́bi bá lógo, báwo ni iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa láre yóo ti lógo tó?
10 Àní ohun tí ó lógo tẹ́lẹ̀ kò tún lógo mọ́ nítorí ohun mìíràn tí ògo tirẹ̀ ta á yọ.
11 Nítorí bí ohun tí yóo pada di asán bá lógo, mélòó-mélòó ni ti ohun tí yóo wà títí laelae?
12 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ní irú ìrètí yìí, a ń fi ìgboyà pupọ sọ̀rọ̀.
13 A kò dàbí Mose tí ó fi aṣọ bojú rẹ̀, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà rí ògo ojú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni ògo tíí ṣá ni.