6 Ìdí nìyí tí a fi gba Titu níyànjú pé, nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí láàrin yín, kí ó kúkú ṣe é parí.
7 Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ní, tí ẹ sì ní lọpọlọpọ: igbagbọ, ọ̀rọ̀ sísọ, ìmọ̀, ati ìtara ní ọ̀nà gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tí ẹ ní sí wa. A fẹ́ kí ìtara yín túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìfẹ́ pẹlu.
8 N kò pa èyí láṣẹ. Mo fi àpẹẹrẹ ìtara àwọn ẹlòmíràn siwaju yín láti fi dán yín wò ni, bóyá ẹ ní ìfẹ́ tòótọ́ tabi ẹ kò ní.
9 Nítorí ẹ mọ oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi, pé nítorí tiwa, òun tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ di aláìní, kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípa àìní tirẹ̀.
10 Èrò mi lórí ọ̀rọ̀ yìí ni pé ohun tí ó dára jùlọ fun yín ni. Nígbà tí kì í tíí ṣe pé ẹ ti ń ṣe é nìkan ni, ṣugbọn tìfẹ́tìfẹ́ ni ẹ ti fi ń ṣe é láti ọdún tí ó kọjá,
11 ó tó àkókò wàyí, ẹ ṣe é parí. Irú ìtara tí ẹ fẹ́ fi ṣe é ni kí ẹ fi parí rẹ̀. Kí ẹ ṣe é gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ní tó.
12 Bí ìfẹ́ láti mú ọrẹ wá bá wà, Ọlọrun gba ohun tí eniyan bá mú wá. Ọlọrun kò bèèrè ohun tí eniyan kò ní.