1 Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu.
2 Abrahamu bí Isaaki, Isaaki bí Jakọbu, Jakọbu bí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀.
3 Juda bí Peresi ati Sera, ìyá wọn ni Tamari. Peresi bí Hesironi, Hesironi bí Ramu.
4 Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bí Naṣoni, Naṣoni bí Salimoni.
5 Salimoni bí Boasi, ìyá Boasi ni Rahabu, Boasi bí Obedi. Ìyá Obedi ni Rutu. Obedi bí Jese.
6 Jese bí Dafidi ọba.Dafidi bí Solomoni. Aya Uraya tẹ́lẹ̀ ni ìyá Solomoni.
7 Solomoni bí Rehoboamu, Rehoboamu bí Abija, Abija bí Asa.