Matiu 13 BM

Òwe Afunrugbin

1 Ní ọjọ́ kan náà, Jesu jáde kúrò nílé, ó lọ jókòó létí òkun.

2 Ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wọ inú ọkọ̀ ojú omi kan. Ó jókòó níbẹ̀, àwọn eniyan bá dúró ní etí òkun.

3 Ó sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ fún wọn pẹlu òwe. Ó ní: “Ní ọjọ́ kan, afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn.

4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn, àwọn irúgbìn kan bọ́ sẹ́bàá ọ̀nà. Àwọn ẹyẹ bá wá ṣà á jẹ.

5 Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ olókùúta tí kò ní erùpẹ̀ pupọ. Lọ́gán ó yọ sókè, nítorí kò ní erùpẹ̀ tí ó jinlẹ̀.

6 Ṣugbọn nígbà tí oòrùn mú, ó jó o pa, nítorí kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; ó bá rọ.

7 Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin igi ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí wọ́n yọ, ẹ̀gún fún wọn pa.

8 Ṣugbọn àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ rere, wọ́n sì ń so èso, àwọn mìíràn ń so ọgọọgọrun-un, àwọn mìíràn ọgọọgọta, àwọn mìíràn, ọgbọọgbọn.

9 “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

Ìdí tí Jesu Fi Ń Lo Òwe

10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń fi òwe bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀?”

11 Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a fi àṣírí ìmọ̀ ìjọba ọ̀run hàn, a kò fihan àwọn yòókù wọnyi.

12 Nítorí ẹni tí ó bá ní nǹkan, òun ni a óo tún fún sí i, kí ó lè ní ànító ati àníṣẹ́kù. Ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀.

13 Ìdí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nìyí, nítorí wọ́n lajú sílẹ̀ ni, ṣugbọn wọn kò ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn.

14 Báyìí ni àsọtẹ́lẹ̀ Aisaya ṣe ṣẹ sí wọn lára, nígbà tí ó sọ pé.‘Ní ti gbígbọ́, ẹ óo gbọ́,ṣugbọn kò ní ye yín;ní ti pé kí ẹ ríran, ẹ óo wò títí,ṣugbọn ẹ kò ní rí nǹkankan.

15 Ọkàn àwọn eniyan yìí ti le,etí wọn ti di,wọ́n sì ti di ojú wọn.Kí wọn má baà fi ojú wọn ríran,kí wọn má baà fi etí wọn gbọ́ràn,kí wọn má baà mòye,kí wọn má baà yipada,kí n wá gbà wọ́n là.’

16 “Ṣugbọn ẹ̀yin ṣe oríire tí ojú yín ríran, tí etí yín sì gbọ́ràn.

17 Nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀pọ̀ àwọn wolii ati àwọn olódodo dàníyàn láti rí àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rí, ṣugbọn wọn kò rí wọn; wọ́n fẹ́ gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́ ṣugbọn wọn kò gbọ́.

Ìtumọ̀ Òwe Afunrugbin

18 “Ẹ gbọ́ ìtumọ̀ òwe afunrugbin.

19 Ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run, tí nǹkan tí ó gbọ́ kò yé e, tí èṣù wá, tí ó mú ohun tí a gbìn sọ́kàn rẹ̀ lọ: òun ni irúgbìn ti ẹ̀bá ọ̀nà.

20 Irúgbìn ti orí ilẹ̀ olókùúta ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á lẹsẹkẹsẹ.

21 Ṣugbọn nítorí kò ní gbòǹgbò ninu ara rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà yóo wà fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tí inúnibíni tabi ìṣòro bá dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, lẹsẹkẹsẹ a kùnà.

22 Ti ààrin igi ẹlẹ́gùn-ún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí àníyàn ayé yìí ati ìtànjẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, tí kò fi so èso.

23 Ṣugbọn èyí tí a fún sórí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ọ̀rọ̀ náà yé, tí ó wá ń so èso, nígbà mìíràn, ọgọrun-un; nígbà mìíràn, ọgọta; nígbà mìíràn, ọgbọ̀n.”

Òwe Èpò láàrin Ọkà

24 Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Bí ìjọba ọ̀run ti rí nìyí. Ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀.

25 Nígbà tí àwọn eniyan sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó gbin èpò sáàrin ọkà, ó bá lọ.

26 Nígbà tí ọkà dàgbà, tí ó yọ ọmọ, èpò náà dàgbà.

27 Àwọn ẹrú baálé náà bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, ‘Alàgbà, ṣebí irúgbìn rere ni o gbìn sí oko, èpò ti ṣe débẹ̀?’

28 Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’ Àwọn ẹrú rẹ̀ ní, ‘Ṣé kí á lọ tu wọ́n dànù?’

29 Ó bá dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Bí ẹ bá wí pé ẹ̀ ń tu èpò, ẹ óo tu ọkà náà.

30 Ẹ jẹ́ kí àwọn mejeeji jọ dàgbà pọ̀ títí di ìgbà ìkórè. Ní àkókò ìkórè, n óo sọ fún àwọn olùkórè pé: ẹ kọ́ kó èpò jọ, kí ẹ dì wọ́n nítìí-nítìí, kí ẹ dáná sun ún. Kí ẹ wá kó ọkà jọ sinu abà mi.’ ”

Òwe Wóró Musitadi kan ati Ìwúkàrà

31 Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Báyìí ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí wóró musitadi tí ẹnìkan gbìn sinu oko rẹ̀.

32 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn, sibẹ nígbà tí ó bá dàgbà, a tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ. A di igi, tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run óo wá ṣe ìtẹ́ wọn lára ẹ̀ka rẹ̀.”

33 Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Ìjọba ọ̀run dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.”

Ìlò Òwe

34 Jesu sọ gbogbo nǹkan wọnyi fún àwọn eniyan ní òwe. Kò sọ ohunkohun fún wọn láì lo òwe;

35 kí ọ̀rọ̀ tí wolii ti sọ lè ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé,“Bí òwe bí òwe ni ọ̀rọ̀ mi yóo jẹ́.N óo sọ àwọn ohun tí ó ti wà ní àṣírí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.”

Ìtumọ̀ Òwe Èpò ninu Oko Ọkà

36 Nígbà tí Jesu kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, ó lọ sinu ilé. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ pé, “Ṣe àlàyé òwe èpò inú oko fún wa.”

37 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó fúnrúgbìn rere ni Ọmọ-Eniyan.

38 Ayé ni oko tí ó fúnrúgbìn sí. Irúgbìn rere ni àwọn ọmọ ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ọmọ èṣù.

39 Ọ̀tá tí ó fọ́n èpò ni èṣù. Ìkórè ni ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli ni olùkórè.

40 Nítorí náà, bí wọn tíí kó èpò jọ tí wọn ń sun ún ninu iná, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ìgbẹ̀yìn ayé.

41 Ọmọ-Eniyan yóo rán àwọn angẹli rẹ̀, wọn yóo kó gbogbo àwọn amúni-ṣìnà ati àwọn arúfin kúrò ninu ìjọba rẹ̀.

42 Wọn yóo sọ wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.

43 Àwọn olódodo yóo wá máa ràn bí oòrùn ninu ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.

Òwe Ìṣúra Iyebíye tí Wọ́n Fi Pamọ́

44 “Báyìí ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí ìṣúra iyebíye kan tí wọ́n fi pamọ́ ninu ilẹ̀. Nígbà tí ẹnìkan rí i, ó bò ó mọ́lẹ̀, ó lọ tayọ̀tayọ̀, ó ta ohun gbogbo tí ó ní, ó bá ra ilẹ̀ náà.

Òwe Ìlẹ̀kẹ̀

45 “Báyìí tún ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí ọkunrin oníṣòwò kan tí ó ń wá ìlẹ̀kẹ̀ olówó iyebíye kan.

46 Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó dára pupọ, ó lọ ta ohun gbogbo tí ó ní, ó bá rà á.

Òwe Àwọ̀n

47 “Báyìí tún ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí àwọ̀n tí a dà sinu òkun, tí ó kó oríṣìíríṣìí ẹja.

48 Nígbà tí ó kún, wọ́n fà á lọ sí èbúté, wọ́n jókòó, wọ́n ṣa àwọn ẹja tí ó dára jọ sinu garawa, wọ́n sì da àwọn tí kò wúlò nù.

49 Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli yóo wá, wọn óo yanjú àwọn eniyan burúkú kúrò láàrin àwọn olódodo,

50 wọn yóo jù wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.”

Nǹkan Titun ati Nǹkan Àtijọ́ ninu Àpò Ìṣúra

51 Jesu bi wọ́n pé, “Ṣé gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ye yín?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”

52 Ó wá sọ fún wọn pé, “Nítorí èyí ni amòfin tí ó bá ti kọ́ nípa ìjọba ọ̀run ṣe dàbí baálé ilé kan, tí ó ń mú nǹkan titun ati nǹkan àtijọ́ jáde láti inú àpò ìṣúra rẹ̀.”

Àwọn Ará Nasarẹti Kọ Jesu

53 Lẹ́yìn tí Jesu ti parí gbogbo àwọn òwe wọnyi, ó kúrò níbẹ̀.

54 Nígbà tí ó dé ìlú baba rẹ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn lọ́nà tí ó yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ń sọ pé, “Níbo ni eléyìí ti ní irú ọgbọ́n yìí? Níbo ni ó ti rí agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu báyìí?

55 Àbí ọmọ gbẹ́nà-gbẹ́nà yẹn kọ́ ni? Tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Maria, tí àwọn arakunrin rẹ̀ ń jẹ́ Jakọbu ati Josẹfu ati Simoni ati Judasi?

56 Gbogbo àwọn arabinrin rẹ̀ kọ́ ni wọ́n wà lọ́dọ̀ wa níhìn-ín? Níbo ni ó wá ti rí gbogbo nǹkan wọnyi?”

57 Wọ́n sì kọ̀ ọ́.Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Kò sí wolii tí kò níyì àfi ní ìlú baba rẹ̀ ati ní ilé rẹ̀.”

58 Kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu pupọ níbẹ̀ nítorí wọn kò ní igbagbọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28