Matiu 12 BM

Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Jesu Ń Já Ọkà ní Ọjọ́ Ìsinmi

1 Ní àkókò náà Jesu ń la oko ọkà kan kọjá ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu. Ebi ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń jẹ ẹ́.

2 Nígbà tí àwọn Farisi rí i, wọ́n wí fún un pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi.”

3 Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò kà nípa ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀?

4 Bí wọ́n ti wọ inú ilé Ọlọrun lọ, tí wọ́n sì jẹ burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, èyí tí ó lòdì sí òfin fún òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ láti jẹ bíkòṣe fún àwọn alufaa nìkan?

5 Tabi ẹ kò kà ninu ìwé Òfin pé iṣẹ́ àwọn alufaa ninu Tẹmpili ní Ọjọ́ Ìsinmi a máa mú wọn ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́? Sibẹ wọn kò jẹ̀bi.

6 Mo sọ fun yín pé ẹni tí ó ju Tẹmpili lọ ló wà níhìn-ín yìí.

7 Bí ó bá jẹ́ pé ìtumọ̀ gbolohun yìí ye yín ni, pé: ‘Àánú ṣíṣe ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú’ ẹ kì bá tí dá ẹ̀bi fún aláìṣẹ̀.

8 Nítorí Ọmọ-Eniyan ni Oluwa Ọjọ́ Ìsinmi.”

Ọkunrin tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ

9 Lẹ́yìn èyí, Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí inú ilé ìpàdé wọn.

10 Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bá òfin mu láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Kí wọ́n baà lè rí ẹ̀sùn fi kàn án ni wọ́n fi bèèrè ìbéèrè yìí.

11 Ó bá bi wọ́n báyìí pé, “Ta ni ninu yín tí yóo ní aguntan kan, bí ọ̀kan náà bá jìn sí kòtò ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á jáde?

12 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí eniyan ti sàn ju aguntan lọ, ó tọ́ láti ṣe rere ní Ọjọ́ Ìsinmi.”

13 Ó bá sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.”Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò gẹ́gẹ́ bí ekeji.

14 Àwọn Farisi bá jáde lọ láti gbèrò nípa rẹ̀, bí wọn óo ṣe lè pa á.

Iranṣẹ Ọlọrun

15 Nígbà tí Jesu mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó bá kúrò níbẹ̀. Ọpọlọpọ eniyan sì tẹ̀lé e, ó sì wo gbogbo wọn sàn.

16 Ó kìlọ̀ fún wọn kí wọn má ṣe polongo òun,

17 kí ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ lè ṣẹ pé,

18 “Wo ọmọ mi tí mo yàn,àyànfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi yọ̀ mọ́Èmi óo fi Ẹ̀mí mi sí i lára,yóo kéde ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu.

19 Kò ní ṣàròyé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní pariwo,bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ ohùn rẹ̀ ní títì.

20 Kò ní dá igi tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó tẹ̀ sí meji.Kò ní pa iná tí ó ń jó bẹ́lúbẹ́lú,títí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ yóo fi borí.

21 Ninu orúkọ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu yóo ní ìrètí.”

Jesu ati Beelisebulu

22 Nígbà náà wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu tí ó ní ẹ̀mí èṣù; ẹ̀mí èṣù yìí ti fọ́ ọ lójú, ó sì mú kí ó yadi. Jesu bá wò ó sàn; ọkunrin náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì ríran.

23 Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń wí pé, “Ó ha lè jẹ́ pé ọmọ Dafidi nìyí bí?”

24 Ṣugbọn nígbà tí àwọn Farisi gbọ́, wọ́n ní, “Ojú lásán kọ́ ni ọkunrin yìí fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde; agbára Beelisebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó ń lò.”

25 Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń rò. Ó bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìlúkílùú tabi ilékílé tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá ń bá ara wọn jà yóo tú.

26 Bí Satani bá ń lé Satani jáde, ara rẹ̀ ni ó ń gbé ogun tì. Báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe lè dúró?

27 Bí ó bá jẹ́ pé agbára Beelisebulu ni èmi fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára wo ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà, àwọn ọmọ yín ni yóo ṣe onídàájọ́ yín.

28 Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọrun ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọrun ti dé ba yín.

29 “Báwo ni ẹnìkan ṣe lè wọ ilé alágbára lọ, kí ó kó o lẹ́rù, bí kò bá kọ́kọ́ de alágbára náà? Bí ó bá kọ́kọ́ dè é ni yóo tó lè kó o lẹ́rù.

30 “Ẹni tí kò bá ṣe tèmi, ó lòdì sí mi. Ẹni tí kò bá máa bá mi kó nǹkan jọ, ó ń fọ́nká ni.

31 Ìdí nìyí tí mo fi sọ fun yín pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati gbogbo ìsọ̀rọ̀ òdì ni a óo dárí rẹ̀ ji eniyan; ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì.

32 Ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ọmọ-Eniyan yóo rí ìdáríjì. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì láyé yìí ati ní ayé tí ń bọ.

Igi ati Èso Rẹ̀

33 “Bákan-meji ni. Ninu kí ẹ tọ́jú igi, kí ó dára, kí èso rẹ̀ sì dára, tabi kí ẹ ba igi jẹ́, kí èso rẹ̀ náà sì bàjẹ́. Èso igi ni a fi ń mọ igi.

34 Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀ yìí! Báwo ni ọ̀rọ̀ yín ti ṣe lè dára nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò dára? Nítorí ohun tí ó bá kún inú ọkàn ni ẹnu ń sọ jáde.

35 Ẹni rere a máa sọ ọ̀rọ̀ rere jáde láti inú ìṣúra rere; eniyan burúkú a sì máa sọ ọ̀rọ̀ burúkú jáde láti inú ìṣúra burúkú.

36 “Ṣugbọn mo sọ fun yín pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí eniyan bá ń sọ láì ronú ni yóo dáhùn fún ní ọjọ́ ìdájọ́.

37 Nítorí nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo fi dá ọ láre; nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo sì fi dá ọ lẹ́bi.”

Àwọn Juu Fẹ́ Àmì láti Ọ̀dọ̀ Jesu

38 Ní àkókò náà ni àwọn kan ninu àwọn amòfin ati ninu àwọn Farisi bi í pé, “Olùkọ́ni, a fẹ́ rí àmì láti ọwọ́ rẹ.”

39 Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìran burúkú ati ìran oníbọkúbọ ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fi fún un àfi àmì Jona wolii.

40 Nítorí bí Jona ti wà ninu ẹja ńlá fún ọjọ́ mẹta tọ̀sán-tòru, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo wà ninu ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹta, tọ̀sán-tòru.

41 Àwọn ará Ninefe yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́, wọn yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí wọ́n ronupiwada nítorí iwaasu tí Jona wà fún wọn. Wò ó, ẹni tí ó ju Jona lọ ló wà níhìn-ín.

42 Ọbabinrin láti ilẹ̀ gúsù yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́ yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí ó wá láti ọ̀nà jíjìn láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni. Ẹ wò ó, ẹni tí ó ju Solomoni lọ ló wà níhìn-ín.

Ẹ̀mí-Èṣù tún Pada sí Ilé Rẹ̀

43 “Nígbà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ẹnìkan, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ilẹ̀ gbígbẹ láti sinmi. Ó ń wá ibi tí yóo fi ṣe ibùgbé, ṣugbọn kò rí.

44 Ó bá ni, ‘N óo tún pada sí ilé mi, níbi tí mo ti jáde kúrò.’ Nígbà tí ó débẹ̀, ó rí i pé ibẹ̀ ṣófo, ati pé a ti gbá a, a sì ti tọ́jú rẹ̀ dáradára.

45 Ó bá lọ, ó kó àwọn ẹ̀mí meje mìíràn lẹ́yìn tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n bá wọlé, wọ́n ń gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìran burúkú yìí.”

Ìyá Jesu ati Àwọn Arakunrin Rẹ̀

46 Bí Jesu ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ ni ìyá rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀ bá dé, wọ́n dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. [

47 Ẹnìkan sọ fún un pé, “Ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”]

48 Jesu dá a lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi? Àwọn ta sì ni arakunrin mi?”

49 Ó bá nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní, “Wò ó ìyá mi ati àwọn arakunrin mi nìwọ̀nyí.

50 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, òun ni arakunrin mi ati arabinrin mi ati ìyá mi.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28