1 Nígbà tí Jesu parí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi, ó kúrò ní Galili, ó dé ìgbèríko Judia ní òdìkejì odò Jọdani.
2 Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń tẹ̀lé e tí ó sì wòsàn níbẹ̀.
3 Àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò; wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà pé kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún ìdí kankan?”
4 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀, takọ-tabo ni ó dá wọn,
5 tí ó sì wí pé, ‘Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo fi fi baba ati ìyá rẹ́ sílẹ̀ tí yóo fara mọ́ iyawo rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo wá di ara kan?’
6 Èyí ni pé wọn kì í tún ṣe ẹni meji mọ́, bíkòṣe ọ̀kan. Nítorí náà ohun tí Ọlọrun bá ti so pọ̀, eniyan kò gbọdọ̀ yà á.”
7 Wọ́n bá tún bi í pé, “Kí ló dé tí Mose fi pàṣẹ pé kí ọkọ fún aya ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, kí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀?”
8 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Nítorí líle ọkàn yín ni Mose fi gbà fun yín láti kọ aya yín sílẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.
9 Mo sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí kò bá jẹ́ nítorí àgbèrè, tí ó bá fẹ́ ẹlòmíràn, ó ṣe àgbèrè.”
10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí ọ̀ràn láàrin ọkunrin ati obinrin bá rí bẹ́ẹ̀, kò ṣe anfaani láti gbeyawo.”
11 Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó lè gba nǹkan yìí, àfi àwọn tí Ọlọrun bá fi fún láti gbà á.
12 Nítorí àwọn ẹlòmíràn jẹ́ akúra kí á tó bí wọn, eniyan sọ àwọn mìíràn di akúra; àwọn ẹlòmíràn sì sọ ara wọn di akúra nítorí ti ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gba èyí, kí ó gbà á.”
13 Ní àkókò yìí ni wọ́n gbé àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ Jesu, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì súre fún wọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí wọn gbé wọn wá wí.
14 Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má dí wọn lọ́nà, nítorí ti irú wọn ni ìjọba ọ̀run.”
15 Ó bá gbé ọwọ́ lé wọn; ó sì kúrò níbẹ̀.
16 Nígbà kan, ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Olùkọ́ni, nǹkan rere wo ni kí n ṣe kí n lè ní ìyè ainipẹkun?”
17 Jesu sọ fún un pé, “Nítorí kí ni o ṣe ń bi mí nípa ohun rere? Ẹni rere kanṣoṣo ni ó wà. Bí o bá fẹ́ wọ inú ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”
18 Ó bi Jesu pé, “Òfin bí irú èwo?”Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké.
19 Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ. Ati pé, fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.”
20 Ọdọmọkunrin náà sọ fún Jesu pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti pamọ́. Kí ni ó tún kù kí n ṣe?”
21 Jesu sọ fún un pé, “Bí o bá fẹ́ ṣe àṣepé, lọ ta dúkìá rẹ, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka; o óo sì ní ìṣúra ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, máa tẹ̀lé mi.”
22 Nígbà tí ọdọmọkunrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò níbẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́ nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ.
23 Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba ọ̀run.
24 Mo tún ń wí fun yín pé yóo rọrùn fún ràkúnmí láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun lọ.”
25 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́, ẹnu yà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni yóo rí ìgbàlà?”
26 Jesu wò wọ́n lójú, ó sọ fún wọn pé, “Èyí kò ṣeéṣe fún eniyan; ṣugbọn ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.”
27 Peteru bá bi í pé, “Wò ó, àwa ti fi ilé ati ọ̀nà sílẹ̀, a wá ń tẹ̀lé ọ. Kí ni yóo jẹ́ èrè wa?”
28 Jesu sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, nígbà tí ó bá di àkókò àtúndá ayé, tí Ọmọ-Eniyan bá jókòó lórí ìtẹ́ ìgúnwà rẹ̀, ẹ̀yin náà tí ẹ tẹ̀lé mi yóo jókòó lórí ìtẹ́ mejila, ẹ óo máa ṣe ìdájọ́ lórí ẹ̀yà Israẹli mejila.
29 Gbogbo ẹni tí ó bá sì fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, baba tabi ìyá, ọmọ tabi ilẹ̀ sílẹ̀, nítorí orúkọ mi, yóo gba ìlọ́po-ìlọ́po ní ọ̀nà ọgọrun-un, yóo sì tún jogún ìyè ainipẹkun.
30 Ọpọlọpọ tí ó jẹ́ ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn; àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú.