Matiu 10 BM

Jesu fún Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Mejila Láṣẹ

1 Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila sọ́dọ̀, ó fún wọn ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ati láti máa ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àrùn ati àìsàn.

2 Orúkọ àwọn aposteli mejila náà nìwọ̀nyí: Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀.

3 Filipi ati Batolomiu, Tomasi ati Matiu agbowó-odè, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Tadiu.

4 Simoni ará Kenaani ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Iṣẹ́ tí Jesu Rán Àwọn Aposteli Mejila

5 Àwọn mejila yìí ni Jesu rán níṣẹ́, ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má gba ọ̀nà ìlú àwọn tí kì í ṣe Juu lọ; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má wọ ìlú àwọn ará Samaria.

6 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ tọ àwọn aguntan ilé Israẹli tí ó sọnù lọ.

7 Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa waasu pé, ‘Ìjọba ọ̀run súnmọ́ tòsí!’

8 Ẹ máa wo aláìsàn sàn; ẹ máa jí àwọn òkú dìde; ẹ máa sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́; ẹ máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ rí agbára wọnyi gbà. Ọ̀fẹ́ ni kí ẹ máa lò wọ́n.

9 Ẹ má fi owó wúrà tabi fadaka tabi idẹ sinu àpò yín.

10 Ẹ má mú àpò tí wọ́n fi ń ṣagbe lọ́wọ́ lọ. Ẹ má mú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji. Ẹ má wọ bàtà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́. Oúnjẹ òṣìṣẹ́ tọ́ sí i.

11 “Bí ẹ bá dé ìlú tabi ìletò kan, ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí bí ẹni tí ó yẹ kan bá wà níbẹ̀; lọ́dọ̀ rẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò níbẹ̀.

12 Nígbà tí ẹ bá wọ inú ilé kan lọ, ẹ kí wọn pé, ‘Alaafia fún ilé yìí.’

13 Bí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ bá wà ninu ilé náà, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó wà níbẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó pada sọ́dọ̀ yín.

14 Bí ẹnìkan kò bá gbà yín sílé, tabi tí kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò ninu ilé tabi ìlú náà, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀.

15 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo sàn fún ilẹ̀ Sodomu ati ti Gomora ní ọjọ́ ìdájọ́, ju ìlú náà lọ!

Inúnibíni tí Ó Ń Bọ̀

16 “Ẹ ṣe akiyesi pé mò ń ran yín lọ bí aguntan sáàrin ìkookò. Nítorí náà ẹ gbọ́n bí ejò, kí ẹ sì níwà tútù bí àdàbà.

17 Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn eniyan, nítorí wọn yóo fà yín lọ siwaju ìgbìmọ̀ láti fẹ̀sùn kàn yín; wọn yóo nà yín ninu àwọn ilé ìpàdé wọn.

18 Wọn yóo mu yín lọ jẹ́jọ́ níwájú àwọn gomina ati níwájú àwọn ọba nítorí tèmi, kí ẹ lè jẹ́rìí mi níwájú wọn ati níwájú àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu.

19 Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ fún ìdájọ́, ẹ má dààmú nípa ohun tí ẹ óo sọ tabi bí ẹ óo ti sọ ọ́; nítorí Ọlọrun yóo fi ohun tí ẹ óo sọ fun yín ní àkókò náà.

20 Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni yóo máa sọ̀rọ̀, ẹ̀mí Baba yín ni yóo máa sọ̀rọ̀ ninu yín.

21 “Arakunrin yóo fi arakunrin rẹ̀ fún ikú pa; baba yóo fi ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóo gbógun ti àwọn òbí wọn, wọn yóo fi wọ́n fún ikú pa.

22 Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá fara dà á títí dé òpin, òun ni a óo gbà là.

23 Bí wọn bá ṣe inúnibíni yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sí ìlú mìíràn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ kò ní tíì ya gbogbo ìlú Israẹli tán kí Ọmọ-Eniyan tó dé.

24 “Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ.

25 Ó tó fún ọmọ-ẹ̀yìn bí ó bá dàbí olùkọ́ rẹ̀. Ó tó fún ẹrú bí ó bá dàbí oluwa rẹ̀. Bí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelisebulu, kí ni wọn yóo pe àwọn ẹni tí ó ń gbé inú ilé rẹ̀!

Ẹni tí Ó Yẹ Ká Bẹ̀rù

26 “Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù àwọn eniyan. Kò sí ohun tí ó wà ní ìpamọ́, tí kò ní fara hàn. Kò sì sí ohun àṣírí tí a kò ní mọ̀.

27 Ohun tí mo sọ fun yín níkọ̀kọ̀, ẹ sọ ọ́ ní gbangba. Ohun tí wọ́n yọ́ sọ fun yín, ẹ kéde rẹ̀ lórí òrùlé.

28 Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara yín, tí wọn kò lè pa ẹ̀mí yín. Ẹni tí ó yẹ kí ẹ bẹ̀rù ni Ọlọrun tí ó lè pa ẹ̀mí ati ara run ní ọ̀run àpáàdì.

29 Ṣebí meji kọbọ ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́! Sibẹ ọ̀kan ninu wọn kò lè jábọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn Baba yín.

30 Gbogbo irun orí yín ni ó níye.

31 Nítorí náà ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ.

Ìjẹ́wọ́ Kristi níwájú Eniyan

32 “Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run.

33 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo sẹ́ ẹ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run.

Ọ̀rọ̀ nípa Jesu Dá Ìyapa Sílẹ̀

34 “Ẹ má rò pé mo mú alaafia wá sáyé. N kò mú alaafia wá; idà ni mo mú wá.

35 Nítorí mo wá láti dá ìyapa sílẹ̀, láàrin ọmọkunrin ati baba rẹ̀, láàrin ọmọbinrin ati ìyá rẹ̀, ati láàrin iyawo ati ìyá ọkọ rẹ̀.

36 Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni.

37 “Ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba tabi ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi.

38 Bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tẹ̀lé mi, kò yẹ ní tèmi.

39 Ẹni tí ó bá sì fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀; ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi yóo jèrè rẹ̀.

Èrè

40 “Ẹni tí ó bá gbà yín, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.

41 Ẹni tí ó bá gba wolii ní orúkọ wolii yóo gba èrè tí ó yẹ wolii. Ẹni tí ó bá gba olódodo ní orúkọ olódodo yóo gba èrè olódodo.

42 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fún ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi yìí tí ó kéré jùlọ ní ife omi tútù mu, nítorí pé ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28