Matiu 26 BM

Àwọn Juu dìtẹ̀ láti pa Jesu

1 Nígbà tí Jesu parí gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,

2 “Ẹ mọ̀ pé lẹ́yìn ọjọ́ meji ni Àjọ̀dún Ìrékọjá, a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ láti kàn mọ́ agbelebu.”

3 Nígbà náà ni àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú péjọ sí àgbàlá Olórí Alufaa tí ó ń jẹ́ Kayafa.

4 Wọ́n ń gbèrò ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe lè fi ẹ̀tàn mú Jesu kí wọ́n lè pa á.

5 Ṣugbọn wọ́n ń sọ pé, “Kí á má ṣe é ní àkókò àjọ̀dún, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìlú yóo dàrú.”

Obinrin kan Fi Òróró Kun Jesu ní Bẹtani

6 Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, ninu ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí,

7 obinrin kan wọlé tọ̀ ọ́ wá tí ó ní ìgò òróró iyebíye olóòórùn dídùn, ni ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tú u sí orí Jesu níbi tí ó ti ń jẹun.

8 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu rí i, inú bí wọn. Wọ́n ní, “Kí ni ìdí irú òfò báyìí?

9 Nítorí títà ni à bá ta òróró yìí ní owó iyebíye tí à bá fi fún àwọn talaka.”

10 Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, nítorí náà, ó wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń da obinrin yìí láàmú sí? Nítorí iṣẹ́ rere ni ó ṣe sí mi lára.

11 Nígbà gbogbo ni ẹ ní àwọn talaka láàrin yín, ṣugbọn ẹ kò ní máa rí mi láàrin yín nígbà gbogbo.

12 Nítorí nígbà tí obinrin yìí da òróró yìí sí mi lára, ó ṣe é fún ìsìnkú mi ni.

13 Mò ń sọ fun yín dájúdájú, níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé, a óo máa sọ nǹkan tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀.”

Judasi Gbà láti Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá

14 Nígbà náà ni ọ̀kan ninu àwọn mejila, tí ó ń jẹ́ Judasi Iskariotu, jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa.

15 Ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ óo fún mi bí mo bá fi Jesu le yín lọ́wọ́?” Wọ́n bá ka ọgbọ̀n owó fadaka fún un.

16 Láti ìgbà náà ni ó ti ń wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.

Jesu Jẹ Àsè Ìrékọjá pẹlu Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn

17 Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?”

18 Ó bá dáhùn pé, “Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ ọkunrin kan báyìí nígboro kí ẹ sọ fún un pé, ‘Olùkọ́ni ní: Àkókò mi súnmọ́ tòsí; ní ilé rẹ ni èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi yóo ti jẹ àsè Ìrékọjá.’ ”

19 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.

20 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn mejila.

21 Bí wọ́n ti ń jẹun, ó wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ọ̀kan ninu yín yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá.”

22 Ọkàn wọn dàrú pupọ; ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Kò sá lè jẹ́ èmi ni, Oluwa?”

23 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ ninu àwo kan náà pẹlu mi ni ẹni náà tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá.

24 Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.”

25 Nígbà náà ni Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, bi í pé, “Àbí èmi ni, Olùkọ́ni?”Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”

Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa

26 Nígbà tí wọn ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó bá fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbà, ẹ jẹ ẹ́, èyí ni ara mi.”

27 Nígbà tí ó mú ife, ó dúpẹ́, ó fi fún wọn, ó ní “Gbogbo yín ẹ mu ninu rẹ̀.

28 Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan.

29 Mo sọ fun yín, n kò ní mu ọtí èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ náà tí n óo mu ún pẹlu yín ní ọ̀tun ní ìjọba Baba mi.”

30 Lẹ́yìn náà, wọ́n kọ orin kan, wọ́n bá jáde lọ sórí Òkè Olifi.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru Yóo Sẹ́ Òun

31 Nígbà náà Jesu sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi ní alẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan,gbogbo agbo aguntan ni a óo fọ́nká!’

32 “Ṣugbọn lẹ́yìn tí a bá ti jí mi dìde, n óo ṣiwaju yín lọ sí Galili.”

33 Peteru dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo àwọn yòókù bá tilẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ, bíi tèmi kọ́!”

34 Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé ní alẹ́ yìí, kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.”

35 Peteru sọ fún un pé, “Bí mo bá tilẹ̀ níláti bá ọ kú, n kò ní sẹ́ ọ.”Bákan náà ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù sọ.

Adura Jesu ní Gẹtisemani

36 Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ Gẹtisemani. Ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín, èmi ń lọ gbadura lọ́hùn-ún nì.”

37 Ó bá mú Peteru ati àwọn ọmọ Sebede mejeeji lọ́wọ́, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì dààmú.

38 Ó wá sọ fún wọn pé, “Mo ní ìbànújẹ́ ọkàn tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ kú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ máa bá mi ṣọ́nà.”

39 Ó wá tún lọ siwaju díẹ̀ síi, ó dojúbolẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, “Baba mi, bí ó bá ṣeéṣe, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn kì í ṣe ohun tí mo fẹ́ ni ṣíṣe, bíkòṣe ohun tí ìwọ fẹ́.”

40 Ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá wọn tí wọn ń sùn. Ó sọ fún Peteru pé, “Èyí ni pé ẹ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wakati kan?

41 Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò. Ẹ̀mí fẹ́ ṣe é, ṣugbọn ara kò lágbára.”

42 Ó tún lọ gbadura lẹẹkeji. Ó ní, “Baba mi, bí kò bá ṣeéṣe pé kí ife kíkorò yìí fò mí ru, tí ó jẹ́ ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ sí mi, ìfẹ́ tìrẹ ni ṣíṣe.”

43 Ó tún wá, ó tún bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí wọn ń sùn, nítorí oorun ń kùn wọ́n pupọ.

44 Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó pada lọ gbadura ní ẹẹkẹta; ó tún sọ nǹkankan náà.

45 Lẹ́yìn náà ó wá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ tún wà níbi tí ẹ̀ ń sùn, tí ẹ̀ ń sinmi! Ẹ wò ó! Àkókò náà súnmọ́ tòsí tí a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.

46 Ẹ dìde. Ẹ jẹ́ kí á máa lọ. Ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá súnmọ́ tòsí.”

Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá

47 Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni Judasi, ọ̀kan ninu àwọn mejila yọ, pẹlu ọ̀pọ̀ eniyan tí wọ́n mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́. Wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú.

48 Ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá ti fi àmì fún wọn pé, “Ẹni tí mo bá kí, tí mo fi ẹnu kàn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ẹni náà. Ẹ mú un.”

49 Lẹsẹkẹsẹ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ Jesu, ó ní, “Ẹ pẹ̀lẹ́ o, Olùkọ́ni.” Ni ó bá da ẹnu dé e ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.

50 Jesu sọ fún un pé, “Ọ̀rẹ́ kí ló dé o?”Nígbà náà ni àwọn eniyan wá, wọ́n ṣùrù mọ́ Jesu, wọ́n mú un.

51 Ọ̀kan ninu àwọn tí ó wà pẹlu Jesu bá na ọwọ́, ó fa idà yọ, ó sì fi ṣá ẹrú Olórí Alufaa kan, ó gé e létí.

52 Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Ti idà rẹ bọ inú akọ rẹ̀ pada, nítorí gbogbo àwọn tí ó bá ń fa idà yọ, idà ni a óo fi pa wọ́n.

53 Tabi o kò mọ̀ pé mo lè ké pe Baba mi, kí ó fún mi ní ẹgbaagbeje angẹli nisinsinyii?

54 Ṣugbọn bí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀ báwo ni Ìwé Mímọ́ yóo ti ṣe ṣẹ pé bẹ́ẹ̀ ni ó gbọdọ̀ rí?”

55 Jesu bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jáde wá mú mi pẹlu idà ati kùmọ̀ bí ìgbà tí ẹ wá mú olè. Ojoojumọ ni mò ń jókòó ninu Tẹmpili láti kọ́ àwọn eniyan. Ẹ kò mú mi nígbà náà!

56 Ṣugbọn gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ àwọn wolii lè ṣẹ ni.”Gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá fi í sílẹ̀, wọ́n sálọ.

A Mú Jesu Lọ siwaju Ìgbìmọ̀

57 Àwọn tí wọ́n mú Jesu fà á lọ sọ́dọ̀ Kayafa Olórí Alufaa, níbi tí àwọn amòfin ati àwọn àgbà ti pé jọ sí.

58 Peteru ń tẹ̀lé Jesu, ó ń bọ̀ lẹ́yìn patapata, títí ó fi dé àgbàlá Olórí Alufaa. Ó wọlé, ó jókòó pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ láti rí ibi tí gbogbo rẹ̀ yóo yọrí sí.

59 Àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí èké tí ó lè kóbá Jesu kí wọn baà lè pa á.

60 Ṣugbọn wọn kò rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọlọpọ ni àwọn ẹlẹ́rìí-èké tí wọ́n yọjú. Ní ìgbẹ̀yìn àwọn meji kan wá.

61 Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí sọ pé, ‘Mo lè wó Tẹmpili Ọlọrun yìí, kí n sì tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.’ ”

62 Olórí Alufaa bá dìde, ó ní, “O kò fèsì rárá? Àbí o kò gbọ́ ohun tí wọ́n sọ pé o wí?”

63 Ṣugbọn Jesu kò fọhùn. Olórí Alufaa wá sọ fún un pé, “Mo fi Ọlọrun alààyè bẹ̀ ọ́, sọ fún wa bí ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun.”

64 Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnu ara rẹ ni o fi sọ ọ́; ṣugbọn mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé láti ìsinsìnyìí lọ, ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.”

65 Olórí Alufaa bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “O sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àfojúdi tí ó sọ sí Ọlọrun nisinsinyii.

66 Kí ni ẹ rò?”Wọ́n dáhùn pé, “Ikú ni ó tọ́ sí i.”

67 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́ sí i lójú, wọ́n ń sọ ọ́ lẹ́ṣẹ̀ẹ́, wọ́n ń gbá a létí.

68 Wọ́n ń sọ pé, “Ìwọ, Mesaya, sọ ẹni tí ó lù ọ́ fún wa!”

Peteru Sẹ́ Jesu

69 Peteru jókòó lóde ní àgbàlá. Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Galili.”

70 Ṣugbọn Peteru sẹ́ níwájú gbogbo wọn, ó ní, “N kò mọ ohun tí ò ń sọ.”

71 Bí ó ti ń lọ sí ẹnu ọ̀nà, iranṣẹbinrin mìíràn tún rí i, ó bá sọ fún àwọn tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.”

72 Peteru tún sẹ́, ó búra pé, “N kò mọ ọkunrin náà.”

73 Ó ṣe díẹ̀ si, àwọn tí ó dúró níbẹ̀ tọ Peteru lọ, wọ́n sọ fún un pé, “Òtítọ́ ni pé ọ̀kan ninu wọn ni ìwọ náà í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ fihàn bẹ́ẹ̀!”

74 Nígbà náà ni Peteru bẹ̀rẹ̀ sí ṣépè, ó tún ń búra pé, “N kò mọ ọkunrin náà.”Lẹsẹkẹsẹ àkùkọ kọ.

75 Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ, pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.” Ó bá bọ́ sóde, ó sọkún gidigidi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28