1 Nígbà tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, Maria Magidaleni ati Maria keji wá wo ibojì Jesu.
2 Ilẹ̀ mì tìtì, nítorí angẹli Oluwa sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó yí òkúta tí ó wà lẹ́nu ibojì kúrò, ó sì jókòó lórí rẹ̀.
3 Ìrísí rẹ̀ dàbí mànàmáná. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
4 Ẹ̀rù mú kí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ibojì náà gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, kí wọn sì kú sára.
5 Angẹli náà sọ fún àwọn obinrin náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé Jesu tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá.
6 Kò sí níhìn-ín, nítorí ó ti jí dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ. Ẹ wá wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.
7 Ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wéré, pé ó ti jí dìde kúrò ninu òkú. Ó ti ṣáájú yín lọ sí Galili; níbẹ̀ ni ẹ óo ti rí i. Ohun tí mo ní sọ fun yín nìyí.”
8 Àwọn obinrin náà bá yára kúrò níbi ibojì náà pẹlu ìbẹ̀rùbojo ati ayọ̀ ńlá, wọ́n sáré lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
9 Lójijì Jesu pàdé wọn, ó kí wọn, ó ní, “Ẹ pẹ̀lẹ́ o!” Wọ́n bá dì mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n júbà rẹ̀.
10 Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arakunrin mi pé kí wọ́n lọ sí Galili; níbẹ̀ ni wọn yóo ti rí mi.”
11 Bí wọ́n ti ń lọ, àwọn kan ninu àwọn tí wọ́n fi ṣọ́ ibojì lọ sí inú ìlú láti sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún àwọn olórí alufaa.
12 Nígbà tí àwọn olórí alufaa ti forí-korí pẹlu àwọn àgbà, wọ́n wá owó tí ó jọjú fún àwọn ọmọ-ogun náà.
13 Wọ́n sì kọ́ wọn pé, “Ẹ sọ pé, ‘Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá lóru láti jí òkú rẹ̀ nígbà tí a sùn lọ.’
14 Bí ìròyìn yìí bá dé etí gomina, a óo bá a sọ̀rọ̀, kò ní sí ohunkohun tí yóo ṣẹ̀rù bà yín.”
15 Àwọn ọmọ-ogun náà bá gba owó tí wọ́n fún wọn, wọ́n ṣe bí wọ́n ti kọ́ wọn. Èyí náà sì ni ìtàn tí àwọn Juu ń sọ káàkiri títí di òní olónìí.
16 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla lọ sí Galili, sí orí òkè tí Jesu ti sọ fún wọn.
17 Nígbà tí wọn rí i, wọ́n júbà rẹ̀, ṣugbọn àwọn kan ninu wọn ń ṣiyèméjì.
18 Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó sọ fún wọn pé, “A ti fún mi ní gbogbo àṣẹ ní ọ̀run ati ní ayé.
19 Nítorí náà kí ẹ lọ sọ gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn mi; kí ẹ máa ṣe ìrìbọmi fún wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọ ati ti Ẹ̀mí Mímọ́.
20 Ẹ máa kọ́ wọn láti kíyèsí gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Kí ẹ mọ̀ dájú pé mo wà pẹlu yín ní ìgbà gbogbo, títí dé òpin ayé.”