12 Ṣugbọn mo sọ fun yín, Elija ti dé, ṣugbọn àwọn eniyan kò mọ̀ ọ́n; ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí i. Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ-Eniyan yóo sì jìyà lọ́wọ́ wọn.”
13 Ó yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà náà pé nípa Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó ń sọ fún wọn.
14 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan, ọkunrin kan wá sọ́dọ̀ Jesu, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀.
15 Ó ní, “Alàgbà, ṣàánú ọmọ mi, nítorí wárápá a máa gbé e, a sì máa joró pupọ. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà, a máa ṣubú lu iná; ní ọpọlọpọ ìgbà ẹ̀wẹ̀, a máa ṣubú sinu omi.
16 Mo mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣugbọn wọn kò lè wò ó sàn.”
17 Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ ati ìran tí ó bàjẹ́ yìí, ìgbà wo ni n óo wà lọ́dọ̀ yín dà? Ìgbà wo ni n óo sì fara dà á fun yín dà? Ẹ mú ọmọ náà wá síhìn-ín.”
18 Jesu bá pàṣẹ fún ẹ̀mí èṣù náà kí ó jáde kúrò ninu rẹ̀, ara ọmọ náà sì dá láti ìgbà náà.