15 “Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, tètè lọ bá a sọ̀rọ̀, ìwọ rẹ̀ meji péré. Bí ó bá gbà sí ọ lẹ́nu, o ti tún sọ ọ́ di arakunrin rẹ tòótọ́.
16 Bí kò bá gbọ́, tún lọ bá a sọ ọ́, ìwọ ati ẹnìkan tabi ẹni meji; gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu àkọsílẹ̀ pé, ẹ̀rí ẹnu eniyan meji tabi mẹta ni a óo fi mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀.
17 Bí kò bá gba tiwọn, sọ fún ìjọ. Bí kò bá gba ti ìjọ, kà á kún alaigbagbọ tabi agbowó-odè.
18 “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ohunkohun tí ẹ bá dè ní ayé, ó di dídè ní ọ̀run; ohunkohun tí ẹ bá tú ní ayé, ó di títú ní ọ̀run.
19 “Mo tún sọ fun yín pé bí ẹni meji ninu yín bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé nípa ohunkohun tí wọn bá bèèrè, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún wọn láti ọ̀dọ̀ Baba mi tí ń bẹ lọ́run.
20 Nítorí níbi tí ẹni meji tabi mẹta bá péjọ ní orúkọ mi, mo wà níbẹ̀ láàrin wọn.”
21 Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Oluwa, ìgbà mélòó ni arakunrin mi óo ṣẹ̀ mí tí n óo dáríjì í? Ṣé kí ó tó ìgbà meje?”