19 “Mo tún sọ fun yín pé bí ẹni meji ninu yín bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé nípa ohunkohun tí wọn bá bèèrè, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún wọn láti ọ̀dọ̀ Baba mi tí ń bẹ lọ́run.
20 Nítorí níbi tí ẹni meji tabi mẹta bá péjọ ní orúkọ mi, mo wà níbẹ̀ láàrin wọn.”
21 Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Oluwa, ìgbà mélòó ni arakunrin mi óo ṣẹ̀ mí tí n óo dáríjì í? Ṣé kí ó tó ìgbà meje?”
22 Jesu dá a lóhùn pé, “N kò sọ fún ọ pé ìgbà meje; ṣugbọn kí ó tó ìgbà meje lọ́nà aadọrin!
23 Nítorí pé ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ yanjú owó òwò pẹlu àwọn ẹrú rẹ̀.
24 Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣírò owó, wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọ̀kẹ́ àìmọye.
25 Kò ní ohun tí yóo fi san gbèsè yìí, nítorí náà olówó rẹ̀ pàṣẹ pé kí á ta òun ati iyawo rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó ní, kí á fi san gbèsè rẹ̀.