4 Nítorí náà ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọde yìí, òun ni ó jẹ́ eniyan pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run.
5 Ẹni tí ó bá gba ọ̀kan ninu irú àwọn ọmọde wọnyi ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà.
6 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á sọ ọ́ sinu ibú òkun.
7 Ìdájọ́ ńlá ń bẹ fún ayé, nítorí àwọn ohun ìkọsẹ̀. Dandan ni kí àwọn ohun ìkọsẹ̀ dé, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ohun ìkọsẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, ó gbé!
8 “Bí ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àbùkù ọwọ́ tabi ti ẹsẹ̀, jù pé kí o ní ọwọ́ meji tabi ẹsẹ̀ meji kí á sọ ọ́ sinu iná àjóòkú lọ.
9 Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀ yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú meji kí á sọ ọ́ sinu iná ọ̀run àpáàdì lọ.
10 “Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe fi ojú tẹmbẹlu ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi; nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, àwọn angẹli wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ lọ́run nígbà gbogbo. [