9 Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀ yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú meji kí á sọ ọ́ sinu iná ọ̀run àpáàdì lọ.
10 “Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe fi ojú tẹmbẹlu ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi; nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, àwọn angẹli wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ lọ́run nígbà gbogbo. [
11 Nítorí Ọmọ-Eniyan wá láti gba àwọn tí ó ti sọnù là.]
12 “Kí ni ẹ rò? Bí ọkunrin kan bá ní ọgọrun-un aguntan, tí ọ̀kan ninu wọn bá sọnù, ǹjẹ́ ọkunrin náà kò ní fi aguntan mọkandinlọgọrun-un yòókù sílẹ̀ lórí òkè, kí ó lọ wá èyí tí ó sọnù?
13 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, nígbà tí ó bá rí i, inú rẹ̀ yóo dùn sí i ju àwọn mọkandinlọgọrun-un tí kò sọnù lọ.
14 Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run pé kí ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi kí ó ṣègbé.
15 “Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, tètè lọ bá a sọ̀rọ̀, ìwọ rẹ̀ meji péré. Bí ó bá gbà sí ọ lẹ́nu, o ti tún sọ ọ́ di arakunrin rẹ tòótọ́.