4 Kí ọ̀rọ̀ tí wolii nì sọ lè ṣẹ pé,
5 “Ẹ sọ fún ọdọmọbinrin, Sioni, pé,Wo ọba rẹ tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ;pẹlu ìrẹ̀lẹ̀, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,ẹranko tí à ń lò láti rẹrù.”
6 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn.
7 Wọ́n fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ati ọmọ rẹ̀ wá, wọ́n tẹ́ aṣọ lé wọn lórí, Jesu bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn.
8 Ọ̀pọ̀ ninu àwọn eniyan tẹ́ aṣọ wọn sọ́nà; àwọn mìíràn ya ẹ̀ka igi, wọ́n tẹ́ wọn sọ́nà.
9 Àwọn èrò tí ń lọ níwájú, ati àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wá ń kígbe pé,“Hosana fún Ọmọ Dafidi,olùbùkún ni ẹni tí ó wá lórúkọ Oluwa.Ògo ni fún Ọlọrun lókè ọ̀run.”
10 Nígbà tí Jesu wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì. Àwọn ará ìlú ń bèèrè pé, “Ta nìyí?”