41 Nígbà tí àwọn Farisi péjọ pọ̀, Jesu bi wọ́n pé,
42 “Kí ni ẹ rò nípa Mesaya, ọmọ ta ni?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọmọ Dafidi ni.”
43 Ó bá tún bi wọ́n pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe darí Dafidi tí Dafidi fi pe Mesaya ní ‘Oluwa’? Dafidi sọ pé,
44 ‘OLUWA sọ fún Oluwa mi pé:Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mitítí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di ohun ìtìsẹ̀ rẹ.’
45 Bí Dafidi bá pè é ní ‘OLUWA’, báwo ni Mesaya ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
46 Kò sí ẹnìkan tí ó lè dá a lóhùn ọ̀rọ̀ yìí. Láti ọjọ́ náà, ẹnikẹ́ni kò ní ìgboyà láti tún bi í ní ohunkohun mọ́.