2 Wọ́n dè é, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu, gomina, lọ́wọ́.
3 Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rí i pé a dá Jesu lẹ́bi, ó ronupiwada. Ó bá lọ dá ọgbọ̀n owó fadaka pada fún àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà.
4 Ó ní, “Mo ṣẹ̀ ní ti pé mo ṣe ikú pa aláìṣẹ̀.”Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Èwo ló kàn wá ninu rẹ̀? Ẹjọ́ tìrẹ ni.”
5 Judasi bá da owó náà sílẹ̀ ninu Tẹmpili, ó jáde, ó bá lọ pokùnso.
6 Àwọn olórí alufaa mú owó fadaka náà, wọ́n ní, “Kò tọ́ fún wa láti fi í sinu àpò ìṣúra Tẹmpili mọ́ nítorí owó ẹ̀jẹ̀ ni.”
7 Lẹ́yìn tí wọ́n ti forí-korí, wọ́n fi owó náà ra ilẹ̀ amọ̀kòkò fún ìsìnkú àwọn àlejò.
8 Ìdí nìyí ti a fi ń pe ilẹ̀ náà ní, “Ilẹ̀ ẹ̀jẹ̀” títí di òní olónìí.