2 Lẹ́yìn tí ó ti gbààwẹ̀ tọ̀sán-tòru fún ogoji ọjọ́, ebi wá ń pa á.
3 Ni adánniwò bá yọ sí i, ó sọ fún un pé, “Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́ nítòótọ́, sọ fún àwọn òkúta wọnyi kí wọ́n di àkàrà.”
4 Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè, bíkòṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun bá sọ.’ ”
5 Lẹ́yìn náà, Èṣù mú un lọ sí Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ nì, ó gbé e lé góńgó orí Tẹmpili.
6 Ó sọ fún un pé, “Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́ nítòótọ́, bẹ́ sílẹ̀. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,‘Yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ,kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà ọ́,kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.’ ”
7 Jesu sọ fún un pé, “Ó tún wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ”
8 Èṣù tún mú un lọ sórí òkè gíga kan; ó fi gbogbo àwọn ìjọba ayé ati ògo wọn hàn án.