21 “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan; ẹni tí ó bá pa eniyan yóo bọ́ sinu ẹjọ́.’
22 Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹni tí ó bá bínú sí arakunrin rẹ̀ yóo bọ́ sinu ẹjọ́. Ẹni tí ó bá bú arakunrin rẹ̀, yóo jẹ́jọ́ níwájú àwọn ìgbìmọ̀ ìlú. Ẹni tí ó bá sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ yìí’ yóo wà ninu ewu iná ọ̀run àpáàdì.
23 Nítorí náà bí o bá fẹ́ mú ọrẹ wá sórí pẹpẹ ìrúbọ, tí o wá ranti pé arakunrin rẹ ní ọ sinu,
24 fi ọrẹ rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ ìrúbọ, kí o kọ́kọ́ lọ bá arakunrin rẹ, kí ẹ parí ìjà tí ó wà ní ààrin yín ná. Lẹ́yìn náà kí o pada wá rú ẹbọ rẹ.
25 “Tètè bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ rẹ́ nígbà tí ẹ bá jọ ń lọ sí ilé ẹjọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo fà ọ́ fún onídàájọ́. Onídàájọ́ yóo fà ọ́ fún ọlọ́pàá, ọlọ́pàá yóo bá gbé ọ jù sẹ́wọ̀n.
26 Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ìwọ kò ní jáde kúrò níbẹ̀ títí ìwọ yóo fi san gbogbo gbèsè rẹ láìku kọbọ.
27 “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè.’