4 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu.
5 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀,nítorí wọn yóo jogún ayé.
6 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ,nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó.
7 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn aláàánú,nítorí Ọlọrun yóo ṣàánú wọn.
8 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́,nítorí wọn yóo rí Ọlọrun.
9 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó ń mú kí alaafia wà láàrin àwọn eniyan,nítorí Ọlọrun yóo pè wọ́n ní ọmọ rẹ̀.
10 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí eniyan ń ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo,nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.