6 Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbadura, wọ inú yàrá rẹ lọ, ti ìlẹ̀kùn rẹ, kí o gbadura sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san rẹ fún ọ.
7 “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má máa wí nǹkankan náà títí, bí àwọn abọ̀rìṣà ti ń ṣe. Nítorí wọ́n rò pé nípa ọ̀rọ̀ pupọ ni adura wọn yóo ṣe gbà.
8 Ẹ má ṣe fara wé wọn, nítorí Baba yín ti mọ ohun tí ẹ nílò kí ẹ tó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
9 Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbadura:‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run:Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ,
10 kí ìjọba rẹ dé,ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayébí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run.
11 Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí.
12 Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wágẹ́gẹ́ bí àwa náà ti dárí ji àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá.