27 Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, àwọn afọ́jú meji kan tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.”
28 Nígbà tí ó wọ inú ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ lọ. Jesu bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé mo lè wò yín sàn?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa.”
29 Ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú, ó ní, “Kí ó rí fun yín gẹ́gẹ́ bí igbagbọ yín.”
30 Ojú wọn bá là. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gidigidi, ó ní “Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀.”
31 Ṣugbọn nígbà tí wọ́n jáde, ńṣe ni wọ́n ń pòkìkí rẹ̀ káàkiri gbogbo agbègbè náà.
32 Bí àwọn afọ́jú náà ti jáde, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kan mú ọkunrin kan, tí ẹ̀mí èṣù mú kí ó yadi, wá sọ́dọ̀ Jesu.
33 Ṣugbọn bí ó ti lé ẹ̀mí èṣù náà jáde ni odi náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń sọ pé, “A kò rí irú èyí rí ní Israẹli.”