Romu 1 BM

Ìkíni

1 Èmi Paulu, iranṣẹ Kristi Jesu, ni mò ń kọ ìwé yìí. Ọlọrun pè mí, ó fi mí ṣe òjíṣẹ́, ó sì yà mí sọ́tọ̀ láti máa waasu ìyìn rere rẹ̀.

2 Bí a bá wo inú Ìwé Mímọ́, a óo rí i pé àwọn wolii ti kéde ìyìn rere náà tẹ́lẹ̀ rí.

3 Ìyìn rere Ọmọ Ọlọrun tí a bí ninu ìdílé Dafidi nípa ti ara.

4 Ọmọ rẹ̀ yìí ni Ọlọrun fi agbára Ẹ̀mí Mímọ́ yàn nígbà tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú. Òun náà ni Jesu Kristi Oluwa wa,

5 nípa ẹni tí a ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà, tí a sì gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní orúkọ rẹ̀, pé kí gbogbo eniyan lè gba Jesu gbọ́, kí wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

6 Ẹ̀yin tí mò ń kọ ìwé yìí sí náà wà lára àwọn tí Jesu Kristi pè.

7 Gbogbo ẹ̀yin àyànfẹ́ Ọlọrun tí ẹ wà ní Romu, ẹ̀yin tí a pè láti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀.Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi, kí ó wà pẹlu yín.

Paulu Ṣàníyàn láti Lọ sí Romu

8 Kí á tó máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi nípasẹ̀ Jesu Kristi nítorí gbogbo yín; nítorí àwọn eniyan ń ròyìn igbagbọ yín ní gbogbo ayé.

9 Ọlọrun, tí mò ń fọkàn sìn bí mo ti ń waasu ìyìn rere Ọmọ rẹ̀, ni ẹlẹ́rìí mi pé mò ń ranti yín láì sinmi.

10 Mo sì ń bẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo ninu adura mi pé, ó pẹ́ ni, ó yá ni, kí n rí ààyè láti wá sọ́dọ̀ yín, bí Ọlọrun bá fẹ́.

11 Mò ń dàníyàn láti ri yín, kí n lè fun yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí tí yóo túbọ̀ fun yín lágbára.

12 Ohun tí mò ń sọ ni pé mo fẹ́ wà láàrin yín kí n baà lè ní ìwúrí nípa igbagbọ yín, kí ẹ̀yin náà ní ìwúrí nípa igbagbọ mi.

13 Kò yẹ kí ẹ má mọ̀, ará, pé ní ìgbà pupọ ni mo ti fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, kí n lè ní èso láàrin yín bí mo ti ní láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, ṣugbọn nǹkankan ti ń dí mi lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ títí di àkókò yìí.

14 Nítorí pé ati àwọn Giriki tí wọ́n jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n, ati àwọn kògbédè tí kò mọ nǹkan, gbogbo wọn ni mo jẹ ní gbèsè.

15 Ìdí rẹ̀ nìyí tí mo ṣe ń dàníyàn láti waasu ìyìn rere fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Romu náà.

Agbára Ìyìn Rere

16 Ojú kò tì mí láti waasu ìyìn rere Jesu, nítorí ìyìn rere yìí ni agbára Ọlọrun, tí a fi ń gba gbogbo àwọn tí ó bá gbà á gbọ́ là. Ó kọ́kọ́ lo agbára yìí láàrin àwọn Juu, lẹ́yìn náà ó lò ó láàrin àwọn Giriki.

17 Ninu ìyìn rere yìí ni a ti ń fi ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre hàn wá: nípa igbagbọ ni, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí igbagbọ ni ẹni tí a bá dá láre yóo fi yè.”

Gbogbo Aráyé Jẹ̀bi Ẹ̀ṣẹ̀

18 Ojú ọ̀run ti ṣí sílẹ̀, Ọlọrun sì ń tú ibinu rẹ̀ sórí gbogbo eniyan nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú tí wọn ń hù, tí wọ́n fi ń ṣe ìdènà fún òtítọ́.

19 Nítorí ohun tí eniyan lè mọ̀ nípa Ọlọrun ti hàn sí wọn, Ọlọrun ni ó ti fihàn wọ́n.

20 Láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ayé ni ìwà ati ìṣe Ọlọrun, tí a kò lè fi ojú rí ati agbára ayérayé rẹ̀, ti hàn gedegbe ninu àwọn ohun tí ó dá. Nítorí èyí, irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kò ní àwáwí.

21 Wọ́n mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò júbà rẹ̀ bí Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo èrò wọn di asán, òye ọkàn wọn sì ṣókùnkùn.

22 Wọ́n ń ṣe bí ẹni pé wọ́n gbọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ya òmùgọ̀.

23 Wọ́n yí ògo Ọlọrun tí kò lè bàjẹ́ pada sí àwòrán ẹ̀dá tí yóo bàjẹ́; bíi àwòrán eniyan, ẹyẹ, ẹranko ati ejò.

24 Nítorí náà Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ láti máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn.

25 Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọrun pada sí irọ́. Wọ́n ń bọ nǹkan tí Ọlọrun dá, wọ́n ń tẹríba fún wọn, dípò èyí tí wọn ìbá fi máa sin ẹni tí ó dá wọn, ẹni tí ìyìn yẹ fún títí lae. Amin.

26 Nítorí náà, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí ó ti eniyan lójú. Àwọn obinrin wọn ń bá ara wọn ṣe ohun tí kò bójú mu.

27 Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọkunrin wọn. Dípò tí ọkunrin ìbá máa fi bá obinrin lòpọ̀, ọkunrin ati ọkunrin ni wọ́n ń dìde sí ara wọn ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn. Ọkunrin ń bá ọkunrin ṣe ohun ìtìjú, wọ́n wá ń jèrè ìṣekúṣe wọn.

28 Nígbà tí wọn kò ka ìmọ̀ Ọlọrun sí, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ọkàn wọn tí kò tọ́, kí wọn máa ṣe àwọn ohun tí kò yẹ.

29 Wọ́n wá kún fún oríṣìíríṣìí ìwà burúkú: ojúkòkòrò, ìkà, owú jíjẹ, ìpànìyàn, ìrúkèrúdò, ẹ̀tàn, inú burúkú. Olófòófó ni wọ́n,

30 ati abanijẹ́; wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun. Wọ́n jẹ́ aláfojúdi, onigbeeraga, afọ́nnu, ati elérò burúkú; wọn kì í gbọ́ràn sí òbí lẹ́nu;

31 wọn kò sì ní ẹ̀rí ọkàn. Aláìṣeégbẹ́kẹ̀lé ni wọ́n, aláìnífẹ̀ẹ́, ati aláìláàánú.

32 Wọ́n mọ ìlànà ti Ọlọrun; wọ́n mọ̀ pé ikú ni ó tọ́ sí àwọn tí wọn bá ń hu irú ìwà wọnyi; sibẹ kì í ṣe pé wọ́n ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ nìkan, wọ́n tún ń kan sáárá sí àwọn tí ń hùwà bẹ́ẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16