Romu 3 BM

1 Ọ̀nà wo wá ni àwọn Juu fi sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ? Kí ni anfaani ìkọlà?

2 Ó pọ̀ pupọ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. Ekinni, àwọn Juu ni Ọlọrun fún ní ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀.

3 Ẹ lè wá sọ pé, “Anfaani wo ni ó wà ninu èyí nígbà tí àwọn mìíràn ninu wọn kò gbàgbọ́? Ǹjẹ́ aigbagbọ wọn kò sọ ìṣòtítọ́ Ọlọrun di òtúbáńtẹ́?”

4 Rárá o! Ọlọrun níláti jẹ́ olóòótọ́ bí gbogbo eniyan bá tilẹ̀ di onírọ́. Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Kí ìwọ Ọlọrun lè jẹ́ olódodo ninu ọ̀rọ̀ rẹ,kí o lè borí nígbà tí wọ́n bá pè ọ́ lẹ́jọ́.”

5 Bí aiṣododo wa bá mú kí òdodo Ọlọrun fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ni kí á wá wí? Ṣé Ọlọrun kò ṣe ẹ̀tọ́ láti bínú sí wa ni? (Mò ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé eniyan ni Ọlọrun.)

6 Rárá o! Bí Ọlọrun kò bá ní ẹ̀tọ́ láti bínú, báwo ni yóo ṣe wá ṣe ìdájọ́ aráyé?

7 Bí aiṣotitọ mi bá mú kí ògo òtítọ́ Ọlọrun túbọ̀ hàn, kí ni ṣe tí a tún fi ń dá mi lẹ́bi bí ẹlẹ́ṣẹ̀?

8 Ṣé, “Kí á kúkú máa ṣe ibi kí rere lè ti ibẹ̀ jáde?” Bí àwọn onísọkúsọ kan ti ń sọ pé à ń sọ. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yẹ fún ìdálẹ́bi.

Kò Sí Olódodo kan

9 Kí ni kí á rí dìmú ninu ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé àwa Juu sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ ni? Rárá o! Nítorí a ti wí ṣáájú pé ati Juu ati Giriki, gbogbo wọn ni ó wà ní ìkáwọ́ ẹ̀ṣẹ̀.

10 Ó wà ní àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ pé,“Kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ olódodo; kò sí ẹnìkankan.

11 Kò sí ẹni tí òye yé,kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọrun.

12 Gbogbo wọn ti yapa kúrò lójú ọ̀nà,gbogbo wọn kò níláárí mọ́,kò sí ẹni tí ó ń ṣe rere,kò sí ẹnìkan.

13 Ibojì tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀nà ọ̀fun wọn,ẹ̀tàn kún ẹnu wọn;oró paramọ́lẹ̀ wà létè wọn;

14 ẹnu wọn kún fún èpè ati ọ̀rọ̀ burúkú.

15 Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

16 Ọ̀nà jamba ati òṣì ni wọ́n ń rìn.

17 Wọn kò mọ ọ̀nà alaafia.

18 Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ní ọkàn wọn.”

19 A mọ̀ pé ohunkohun tí Òfin bá wí, ó wà fún àwọn tí ó mọ Òfin ni, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rí àwáwí wí, kí gbogbo aráyé lè wà lábẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun.

20 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, bí a bá mú Òfin tí a fi díwọ̀n iṣẹ́ ọmọ eniyan, kò sí ẹ̀dá kan tí a óo dá láre níwájú Ọlọrun. Nítorí òfin níí mú kí eniyan mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀.

Ìdáláre nípa Igbagbọ

21 Ṣugbọn ní àkókò yìí, ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre ti hàn láìsí Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ ti Òfin ati ti àwọn wolii Ọlọrun jẹ́rìí sí i.

22 Gbogbo àwọn tí ó bá gba Jesu gbọ́ yóo yege lọ́dọ̀ Ọlọrun láìsí ìyàtọ̀ kan.

23 Nítorí gbogbo eniyan ló ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọrun.

24 Gbogbo wọn ni Ọlọrun ti ṣe lóore: ó dá wọn láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa ìràpadà tí Kristi Jesu ṣe.

25-26 Jesu yìí ni Ọlọrun fi ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́, nípa ikú rẹ̀. Èyí ni láti fi ọ̀nà tí Ọlọrun yóo fi dá eniyan láre hàn, nítorí pé ó fi ojú fo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dá, nípa ìyọ́nú rẹ̀, kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn ní àkókò yìí, kí ó lè hàn pé olódodo ni òun, ati pé òun ń dá ẹni tí ó bá gba Jesu gbọ́ láre.

27 Ààyè ìgbéraga dà? Kò sí rárá. Nípa irú ìlànà wo ni kò fi sí mọ́? Nípa iṣẹ́ Òfin ni bí? Rárá o! Nípa ìlànà ti igbagbọ ni.

28 Nítorí ohun tí a rí ni pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun ń dá eniyan láre, kì í ṣe nípa pípa Òfin mọ́.

29 Àbí ti àwọn Juu nìkan ni Ọlọrun, kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù? Dájúdájú Ọlọrun àwọn Juu ati ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ni.

30 Nígbà tí ó jẹ́ pé Ọlọrun kanṣoṣo ni ó wà, òun ni ó sì ń dá àwọn tí ó kọlà láre nípa igbagbọ, tí ó tún ń dá àwọn tí kò kọlà láre nípa igbagbọ bákan náà.

31 Ṣé Òfin wá di òtúbáńtẹ́ nítorí igbagbọ ni? Rárá o! A túbọ̀ fi ìdí Òfin múlẹ̀ ni.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16