Romu 2 BM

Ìdájọ́ Òdodo Tí Ọlọrun Ṣe

1 Kò sí àwáwí kankan fún ọ, ìwọ tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. Nǹkan gan-an tí ò ń torí rẹ̀ dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́ ni o fi ń dá ara rẹ lẹ́bi. Nítorí ìwọ náà tí ò ń dáni lẹ́jọ́ ń ṣe àwọn nǹkan gan-an tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́bi fún.

2 Ṣugbọn a mọ̀ pé Ọlọrun ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi.

3 Ìwọ tí ò ń dá àwọn ẹlòmíràn tí ó ń ṣe nǹkan wọnyi lẹ́jọ́, tí ìwọ alára sì ń ṣe nǹkankan náà, ṣé o wá rò pé ìwọ óo bọ́ ninu ìdájọ́ Ọlọrun ni?

4 Àbí o fi ojú tẹmbẹlu ọpọlọpọ oore Ọlọrun ni, ati ìfaradà rẹ̀ ati sùúrù rẹ̀? O kò mọ̀ pé kí o lè ronupiwada ni gbogbo oore tí Ọlọrun ń ṣe,

5 Ṣugbọn nípa oríkunkun ati agídí ọkàn rẹ, ò ń fi ibinu Ọlọrun pamọ́ fún ara rẹ títí di ọjọ́ ibinu ati ìgbà tí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun yóo dé.

6 Ọlọrun yóo san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀;

7 yóo fi ìyè ainipẹkun fún àwọn tí ń fi sùúrù ṣe iṣẹ́ rere nípa lílépa àwọn nǹkan tí ó lógo, tí ó sì lọ́lá, àwọn nǹkan tí kò lè bàjẹ́.

8 Ṣugbọn ní ti àwọn tí ó jẹ́ pé ti ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, ati àwọn tí kò gba òtítọ́, àwọn tí wọ́n gba ohun burúkú, Ọlọrun yóo fi ibinu ati ìrúnú rẹ̀ hàn wọ́n;

9 yóo mú ìpọ́njú ati ìṣòro bá gbogbo àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ ibi. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ kàn, lẹ́yìn náà àwọn Giriki.

10 Ṣugbọn yóo fi ògo, ọlá ati alaafia fún gbogbo àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ fún, lẹ́yìn náà yóo fún àwọn Giriki.

11 Nítorí Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju.

12 Gbogbo àwọn tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ láì lófin, láì lófin náà ni wọn yóo kú. Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ Òfin, tí wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀, òfin náà ni a óo fi ṣe ìdájọ́ wọn.

13 Kì í ṣe àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí Òfin sọ ni Ọlọrun ń dá láre, àwọn tí wọn ń ṣe ohun tí Òfin sọ ni.

14 Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu tí kò mọ Òfin bá ń ṣe ohun tí Òfin sọ bí nǹkan àmútọ̀runwá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ Òfin, wọ́n di òfin fún ara wọn.

15 Irú àwọn wọnyi fihàn pé a ti kọ iṣẹ́ ti Òfin sinu ọkàn wọn. Ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ ninu wọn: àwọn èrò oríṣìíríṣìí tí ó wà ninu wọn yóo máa dá wọn láre tabi kí ó máa dá wọn lẹ́bi,

16 ní ọjọ́ tí Ọlọrun yóo rán Jesu láti ṣe ìdájọ́ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo tí ó wà ninu eniyan gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí mò ń waasu.

Àwọn Juu ati Òfin

17 Ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní Juu, o gbójú lé Òfin, o wá ń fọ́nnu pé o mọ Ọlọrun.

18 O mọ ohun tí Ọlọrun fẹ́. O mọ àwọn ohun tí ó dára jù nítorí a ti fi Òfin kọ́ ọ.

19 O dá ara rẹ lójú bí ẹni tí ó jẹ́ amọ̀nà fún àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn.

20 O pe ara rẹ ní ẹni tí ó lè bá àwọn tí kò gbọ́n wí, olùkọ́ àwọn ọ̀dọ́, ẹni tí ó mọ àwọn nǹkan tí ó jẹ́ kókó ati òtítọ́ tí ó wà ninu Òfin.

21 Ìwọ tí ò ń kọ́ ẹlòmíràn, ṣé o kò ní kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ò ń waasu pé kí eniyan má jalè, ṣé ìwọ náà kì í jalè?

22 Ìwọ tí o sọ pé kí eniyan má ṣe àgbèrè, ṣé ìwọ náà kì í ṣe àgbèrè? Ìwọ tí o kórìíra oriṣa, ṣé o kì í ja ilé ìbọ̀rìṣà lólè?

23 Ìwọ tí ò ń fọ́nnu pé o mọ Òfin, ṣé o kì í mú ẹ̀gàn bá Ọlọrun nípa rírú Òfin?

24 Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Orúkọ Ọlọrun di ohun ìṣáátá láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu nítorí yín.”

25 Ilà tí o kọ ní anfaani, bí o bá ń pa Òfin mọ́. Ṣugbọn tí o bá rú Òfin, bí àìkọlà ni ìkọlà rẹ rí.

26 Ǹjẹ́ bí aláìkọlà bá ń pa àwọn ìlànà òdodo tí ó wà ninu Òfin mọ́, a kò ha ní ka àìkọlà rẹ̀ sí ìkọlà?

27 Ẹni tí a bí ní aláìkọlà tí ó ń pa Òfin mọ́, ó mú ìtìjú bá ìwọ tí a kọ Òfin sílẹ̀ fún, tí o kọlà, ṣugbọn sibẹ tí o jẹ́ arúfin.

28 Kì í ṣe nǹkan ti òde ara ni eniyan fi ń jẹ́ Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìkọlà kì í ṣe kí á fabẹ gé ara.

29 Ṣugbọn láti jẹ́ Juu tòótọ́ jẹ́ ohun àtinúwá; ìkọlà jẹ́ nǹkan ti ọkàn. Nǹkan ti ẹ̀mí ni, kì í ṣe ti inú ìwé. Ìyìn irú ẹni bẹ́ẹ̀ wà lọ́dọ̀ Ọlọrun, kì í ṣe ọ̀dọ̀ eniyan.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16