Romu 8 BM

Ìgbésí-Ayé Onigbagbọ ninu Ẹ̀mí

1 Nisinsinyii, kò sí ìdálẹ́bi kan mọ́ fún àwọn tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu.

2 Ìdí ni pé, agbára Ẹ̀mí, tí ó ń fi ìyè fún àwọn tí ń bá Kristi gbé, ti dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ati kúrò lábẹ́ àṣẹ ikú.

3 Èyí jẹ́ nǹkan tí kò ṣe é ṣe lábẹ́ Òfin, nítorí eniyan kò lè ṣàì dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe é, nígbà tí ó dá ẹ̀bi ikú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu ẹ̀yà ara eniyan. Àní sẹ́, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí eniyan ẹlẹ́ṣẹ̀ láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́.

4 Ọlọrun ṣe èyí kí á lè tẹ̀lé ìlànà Òfin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àní àwa tí ìhùwàsí wa kì í ṣe bíi tí ẹni tí ẹran-ara ń lò ṣugbọn bí àwọn ẹni tí Ẹ̀mí ń darí.

5 Nítorí àwọn tí ó ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ẹran- ara ń lò a máa lépa ìtẹ́lọ́rùn fún ẹran-ara; ṣugbọn àwọn tí Ẹ̀mí ń darí a máa lépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí.

6 Lílépa àwọn nǹkan ti ẹran-ara nìkan a máa yọrí sí ikú, ṣugbọn lílépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí a máa fúnni ní ìyè ati alaafia.

7 Ìdí nìyí tí àwọn tí ń lépa nǹkan ti ẹran-ara nìkan fi jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun, nítorí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè fara wọn sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun; wọn kò tilẹ̀ lè ṣe é rárá ni.

8 Àwọn tí ń ṣe ìfẹ́ ẹran-ara wọn kò lè sin Ọlọrun.

9 Ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí mọ́; Ẹ̀mí ló ń ṣamọ̀nà yín, bí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń gbé inú yín nítòótọ́. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ní Ẹ̀mí Kristi ninu rẹ̀, kì í ṣe ti Kristi.

10 Ṣugbọn bí Kristi bá ń gbé inú yín, bí ara yín yóo tilẹ̀ kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀, sibẹ ẹ̀mí yín yóo wà láàyè nítorí pé Ọlọrun ti da yín láre.

11 Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Ọlọrun, ẹni tí ó jí Jesu dìde kúrò ninu òkú, bá ń gbé inú yín, òun náà tí ó jí Kristi dìde kúrò ninu òkú yóo sọ ara yín, tí yóo kú, di alààyè nípa Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ń gbé inú yín.

12 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kò sí ohunkohun mọ́ tí ó mú wa ní túlààsì pé kí á máa hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí.

13 Nítorí bí ẹ bá hùwà bí àwọn tí ẹran-ara ń darí, kíkú ni ẹ óo kú dandan. Ṣugbọn tí ẹ bá ń rìn lọ́nà ti Ẹ̀mí, tí ẹ kò sì hu ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ẹ óo yè.

14 Nítorí àwọn tí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń darí ni ọmọ Ọlọrun.

15 Ẹ̀mí tí Ọlọrun fun yín kì í ṣe èyí tí yóo tún sọ yín di ẹrú, tí yóo sì máa mu yín bẹ̀rù. Ṣugbọn Ẹ̀mí tí ó sọ yín di ọmọ ni ẹ gbà. Ẹ̀mí yìí náà ni ó jẹ́ kí á lè máa ké pe Ọlọrun pé, “Baba! Baba wa!”

16 Ẹ̀mí kan náà ní ń sọ sí wa lọ́kàn pé ọmọ Ọlọrun ni wá.

17 Wàyí ò, tí a bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá. Tí a bá sì jẹ́ ajogún, a jẹ́ pé àwa pẹlu Kristi ni a óo jọ jogún pọ̀, bí a bá bá Kristi jìyà, a óo bá a gba iyì pẹlu.

Ògo Ayé tí ń bọ̀

18 Mo wòye pé a kò lè fi ìyà ayé yìí wé ọlá tí Ọlọrun yóo dá wa ní ayé tí ń bọ̀ wá.

19 Nítorí gbogbo ẹ̀dá ayé ló ń fi ìwàǹwára nàgà, tí wọn ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo fi àwọn tíí ṣe ọmọ rẹ̀ hàn.

20 Nítorí pé gbogbo ẹ̀dá ayé ló ti pasán, kì í ṣe pé ẹ̀dá ayé fúnra wọn ni wọ́n fẹ́ pasán, ṣugbọn bẹ́ẹ̀ ni ó wu Ẹlẹ́dàá láti yàn án. Sibẹ ìrètí ń bẹ pé:

21 ẹ̀dá ayé pàápàá yóo bọ́ lóko ẹrú, kúrò ninu ipò ìdíbàjẹ́, yóo sì pín ninu ọlá àwọn ọmọ Ọlọrun.

22 Àwa náà rí i pé, títí di òní olónìí, gbogbo ẹ̀dá ayé ni wọ́n ń jẹ̀rora, tí wọ́n sì ń rọbí bí aboyún.

23 Ṣugbọn kì í ṣe ẹ̀dá ayé nìkan ló ń jẹ̀rora. Àní sẹ́, àwa fúnra wa, tí a ti rí Ẹ̀mí Ọlọrun gbà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn rẹ̀ àkọ́kọ́, à ń jẹ̀rora lọ́kàn wa, bí a ti ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo pè wá lọ́mọ rẹ̀, tí yóo sì dá gbogbo ara wa nídè.

24 Nítorí ti ìrètí yìí ni a fi gbà wá là. Ṣebí ohun tí a bá ti fojú rí ti kúrò ní ohun tí à ń retí. Àbí, ta ni í tún máa ń retí ohun tí ó bá ti rí?

25 Ṣugbọn nígbà tí a bá ń retí ohun tí a kò ì tíì fojú rí, dídúró ni à á dúró dè é pẹlu ìfaradà títí yóo fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.

26 Bákan náà, Ẹ̀mí tún ń ràn wá lọ́wọ́ ninu àìlera wa. Nítorí a kò mọ ohun tí ó tọ́ tí à bá máa gbadura fún. Ṣugbọn Ẹ̀mí fúnrarẹ̀ a máa bẹ̀bẹ̀ fún wa lọ́dọ̀ Ọlọrun lọ́nà tí a kò lè fi ẹnu sọ.

27 Ọlọrun, Olùmọ̀ràn ọkàn, mọ èrò tí ó wà lọ́kàn Ẹ̀mí, nítorí Ẹ̀mí níí máa bẹ̀bẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun bí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti fẹ́.

28 Àwa mọ̀ dájú pé Ọlọrun a máa mú kí ohun gbogbo yọrí sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀, àwọn tí ó ti pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé.

29 Nítorí àwọn tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwọn ni ó yà sọ́tọ̀ kí wọ́n lè dàbí Ọmọ rẹ̀, kí Ọmọ rẹ̀ yìí lè jẹ́ àkọ́bí láàrin ọpọlọpọ mọ̀lẹ́bí.

30 Àwọn tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwọn ni ó pè. Àwọn tí ó pè ni ó dá láre. Àwọn tí ó sì dá láre ni ó dá lọ́lá.

Ìfẹ́ Ọlọrun sí Wa nípa Jesu

31 Kí ni kí á wá wí sí gbogbo nǹkan wọnyi? Bí Ọlọrun bá wà lẹ́yìn wa, ta ni lè lòdì sí wa?

32 Ọlọrun, tí kò dá Ọmọ rẹ̀ sí, ṣugbọn tí ó yọ̀ǹda rẹ̀ nítorí gbogbo wa, báwo ni kò ṣe ní fún wa ní ohun gbogbo pẹlu rẹ̀?

33 Ta ni yóo fi ẹ̀sùn kan kan àwọn ẹni tí Ọlọrun ti yàn? Ṣé Ọlọrun ni, òun tí ó dá wọn láre?

34 Àbí ta ni yóo dá wọn lẹ́bi? Dájúdájú, kò lè jẹ́ Kristi, ẹni tí ó kú, àní sẹ́ ẹni tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, tí ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa.

35 Ta ni yóo yà wá kúrò ninu ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni bí, tabi ìṣòro, tabi inúnibíni, tabi ìyàn, tabi òṣì, tabi ewu, tabi idà?

36 Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí rẹ a wà ninu ewu ikú lojoojumọ,wọ́n sì ṣe wá bí aguntan tí wọ́n fẹ́ lọ pa.”

37 Ṣugbọn ninu gbogbo ìrírí wọnyi, a ti borí gbogbo ìṣòro nípa agbára ẹni tí ó fẹ́ràn wa.

38 Nítorí ó dá mi lójú pé, kò sí ohunkohun–ìbáà ṣe ikú tabi ìyè, ìbáà ṣe àwọn angẹli tabi àwọn irúnmọlẹ̀, tabi àwọn ohun ayé òde òní tabi àwọn ti ayé tí ó ń bọ̀,

39 yálà àwọn àlùjọ̀nnú ojú-ọ̀run tabi àwọn ẹbọra inú ilẹ̀; lọ́rọ̀ kan, kò sí ẹ̀dá náà tí ó lè yà wá kúrò ninu ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa nípasẹ̀ Kristi Jesu Oluwa wa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16