Romu 4 BM

Àpẹẹrẹ Abrahamu

1 Kí ni kí á wí nípa Abrahamu baba-ńlá wa nípa ti ara? Kí ni ìrírí rẹ̀?

2 Bí ó bá jẹ́ pé nítorí ohun tí ó ṣe ni Ọlọrun fi dá a láre, ìwọ̀nba ni ohun tí ó lè fi ṣe ìgbéraga. Ṣugbọn kò lè fọ́nnu níwájú Ọlọrun.

3 Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ni pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere.”

4 A kò lè pe èrè tí òṣìṣẹ́ bá gbà ní ẹ̀bùn; ẹ̀tọ́ rẹ̀ ni.

5 Ṣugbọn ẹni tí kò ṣe nǹkankan, ṣugbọn tí ó ṣá ní igbagbọ sí ẹni tí ó ń dá ẹni tí kò yẹ láre, Ọlọrun kà á sí ẹni rere nípa igbagbọ rẹ̀.

6 Dafidi náà sọ̀rọ̀ nípa oríire ẹni tí Ọlọrun kà sí ẹni rere, láìwo iṣẹ́ tí ó ṣe. Ó ní,

7 “Ẹni tí Ọlọrun bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì,tí Ọlọrun bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó ṣoríire.

8 Ẹni tí Oluwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn sì ṣoríire.”

9 Ṣé ẹni tí ó kọlà nìkan ni ó ṣoríire ni, tabi ati ẹni tí kò kọlà náà? Ohun tí a sọ ni pé, “Ọlọrun ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere fún Abrahamu.”

10 Ipò wo ni ó wà tí Ọlọrun fi kà á sí ẹni rere: lẹ́yìn tí ó ti kọlà ni tabi kí ó tó kọlà? Kì í ṣe lẹ́yìn tí ó ti kọlà, kí ó tó kọlà ni.

11 Ó gba àmì ìkọlà bí ẹ̀rí iṣẹ́ rere nípa igbagbọ tí ó ní nígbà tí kò ì tíì kọlà. Nítorí èyí, ó di baba fún gbogbo àwọn tí ó ní igbagbọ láì kọlà, kí Ọlọrun lè kà wọ́n sí ẹni rere;

12 ó sì di baba fún àwọn tí ó kọlà ṣugbọn tí wọn kò gbẹ́kẹ̀lé ilà tí wọ́n kọ, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní irú ọ̀nà igbagbọ tí baba wa Abrahamu ní kí ó tó kọlà.

Ìlérí Ṣẹ nípa Igbagbọ

13 Nítorí kì í ṣe nítorí pé Abrahamu pa Òfin mọ́ ni Ọlọrun fi ṣe ìlérí fún òun ati ìran rẹ̀ pé yóo jogún ayé; nítorí ó gba Ọlọrun gbọ́ ni, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere.

14 Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ń tẹ̀lé ètò Òfin ni yóo jogún ìlérí Ọlọrun, a jẹ́ pé ọ̀ràn àwọn tí ó dúró lórí igbagbọ di òfo, ìlérí Ọlọrun sì di òtúbáńtẹ́.

15 Nítorí òfin ni ó ń mú ibinu Ọlọrun wá. Ṣugbọn níbi tí kò bá sí òfin, kò sí ẹ̀ṣẹ̀.

16 Ìdí nìyí tí ìlérí náà fi jẹ́ ti igbagbọ, kí ó lè jẹ́ ọ̀fẹ́, kí ó sì lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún gbogbo ọmọ Abrahamu. Kì í ṣe fún àwọn tí ó gba ètò ti Òfin nìkan, bíkòṣe fún ẹni tí ó bá ní irú igbagbọ tí Abrahamu ẹni tí ó jẹ́ baba fún gbogbo wa ní.

17 Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Mo ti yàn ọ́ láti di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.” Níwájú Ọlọrun ni Abrahamu wà nígbà tí ó gba ìlérí yìí, níwájú Ọlọrun tí ó gbẹ́kẹ̀lé, Ọlọrun tí ó ń sọ òkú di alààyè, Ọlọrun tí ó ń pe àwọn ohun tí kò ì tíì sí jáde bí ẹni pé wọ́n wá.

18 Abrahamu retí títí, ó gbàgbọ́ pé òun yóo di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti wí, pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo rí.”

19 Igbagbọ rẹ̀ kò yẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ro ti ara rẹ̀ tí ó ti di òkú tán, (nítorí ó ti tó ẹni ọgọrun-un ọdún) ó tún ro ti Sara tí ó yàgàn.

20 Kò fi aigbagbọ ṣiyèméjì sí ìlérí Ọlọrun. Kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni igbagbọ rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i, ó fi ògo fún Ọlọrun

21 nítorí pé ó dá a lójú pé ẹni tí ó ṣe ìlérí lè mú un ṣẹ.

22 Ìdí rẹ̀ nìyí tí Ọlọrun fi ka igbagbọ rẹ̀ sí iṣẹ́ rere fún un.

23 Ṣugbọn kì í ṣe nípa òun nìkan ṣoṣo ni a kọ ọ́ pé a ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere.

24 A kọ ọ́ nítorí ti àwa náà tí a óo kà sí ẹni rere, gbogbo àwa tí a ní igbagbọ ninu ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde kúrò ninu òkú,

25 ẹni tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde fún ìdáláre wa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16