1 Ẹ̀yin ará mi, ohun tí mò ń wí yìí kò ṣe àjèjì si yín (nítorí ẹ̀yin náà mọ òfin), pé òfin de eniyan níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láàyè nìkan.
2 Bí àpẹẹrẹ, òfin igbeyawo de abilekọ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá kú, òfin tí ó de obinrin náà mọ́ ọkọ rẹ̀ kò ṣiṣẹ́ mọ́.
3 Wàyí ò, bí obinrin náà bá lọ bá ọkunrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè, alágbèrè ni a óo pè é. Ṣugbọn tí ọkọ rẹ̀ bá ti kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin igbeyawo, kì í ṣe àgbèrè mọ́, bí ó bá lọ fẹ́ ọkọ mìíràn.
4 Bẹ́ẹ̀ náà ni, ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin náà ti kú ní ti Òfin, nígbà tí ẹ di ara kan náà pẹlu Kristi. Ẹ ti ní ọkọ mìíràn, àní, ẹni tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kí á lè sin Ọlọrun lọ́nà tí yóo yọrí sí rere.
5 Tẹ́lẹ̀ rí, nígbà tí a ti ń ṣe ìfẹ́ inú wa bí ẹlẹ́ran-ara, èrò ọkàn wa a máa fà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Òfin dá wa lẹ́kun rẹ̀, láti tì wá sí ohun tí àyọrísí rẹ̀ jẹ́ ikú.
6 Ṣugbọn nisinsinyii, a ti bọ́ kúrò lábẹ́ Òfin. A ti kú sí ohun tí ó dè wá. Báyìí, a kò sin Ọlọrun lọ́nà àtijọ́ mọ́, àní lọ́nà ti Òfin àkọsílẹ̀, ṣugbọn ní ọ̀nà titun ti Ẹ̀mí.
7 Kí ni kí á wá wí wàyí ò? Ṣé Òfin wá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o! Ṣugbọn ṣá, èmi kì bá tí mọ ẹ̀ṣẹ̀ bí Òfin kò bá fi í hàn mí. Bí àpẹẹrẹ, ǹ bá tí mọ ojúkòkòrò bí Òfin kò bá sọ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.”
8 Àṣẹ yìí ni ẹ̀ṣẹ̀ rí dìrọ̀ mọ́ láti fi ṣiṣẹ́. Ó ń fi èrò oríṣìíríṣìí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí mi lọ́kàn. Bí a bá mú òfin kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ di òkú.
9 Nígbà kan rí mò ń gbé ìgbésí-ayé mi láìsí òfin. Ṣugbọn nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ yọjú pẹlu,
10 ni mo bá kú. Òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá, ni ó wá di ọ̀ràn ikú fún mi.
11 Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ rí ohun dìrọ̀ mọ́ ninu òfin, ó tàn mí jẹ, ó sì pa mí kú.
12 Dájú, ohun mímọ́ ni Òfin, àwọn àṣẹ tí ó wà ninu rẹ̀ náà sì jẹ́ ohun mímọ́, ohun tí ó tọ́, tí ó sì dára.
13 Ǹjẹ́ ohun tí ó dára yìí ni ó ṣe ikú pa mí? Rárá o! Ẹ̀ṣẹ̀ níí ṣekú pani. Kí ẹ̀ṣẹ̀ lè fara rẹ̀ hàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó lo ohun tí ó dára láti pa mí kú, báyìí, ó hàn gbangba pé ibi gan-an ni ẹ̀ṣẹ̀ í ṣe, nítorí ó kó sábẹ́ òfin láti ṣe ibi.
14 Àwa mọ̀ dájú pé Òfin jẹ́ nǹkan ti Ẹ̀mí. Ṣugbọn èmi jẹ́ eniyan ẹlẹ́ran-ara, tí a ti tà lẹ́rú fún ẹ̀ṣẹ̀.
15 Ìwà mi kò yé èmi alára; nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan tí mo bá fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, àwọn nǹkan tí mo kórìíra gan-an ni mò ń ṣe.
16 Níwọ̀n ìgbà tí mo bá ń ṣe àwọn nǹkan tí n kò fẹ́, mò ń jẹ́rìí sí i pé Òfin jẹ́ ohun tí ó dára.
17 Wàyí ò, ó já sí pé kì í ṣe èmi alára ni mò ń hùwà bẹ́ẹ̀, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi.
18 Mo mọ̀ dájú pé, kò sí agbára kan ninu èmi eniyan ẹlẹ́ran-ara, láti ṣe rere, n kò lágbára láti ṣe é.
19 Nítorí kì í ṣe nǹkan rere tí mo fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, ṣugbọn àwọn nǹkan burúkú tí n kò fẹ́, ni mò ń ṣe.
20 Tí ó bá wá jẹ́ pé àwọn nǹkan tí n kò fẹ́ ni mò ń ṣe, a jẹ́ pé kì í ṣe èmi ni mò ń ṣe é, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi.
21 Mo wá rí i wàyí pé, ó ti di bárakú fún mi, pé nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe rere, àwọn nǹkan burúkú ni ó yá sí mi lọ́wọ́.
22 Mo yọ̀ gidigidi ninu ọkàn mi pé Ọlọrun ṣe òfin.
23 Ṣugbọn bí mo ti wòye, àwọn ẹ̀yà ara mi ń tọ ọ̀nà mìíràn, tí ó lòdì sí ọ̀nà tí ọkàn mi fẹ́, ọ̀nà òdì yìí ni ó gbé mi sinu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu àwọn ẹ̀yà ara mi.
24 Irú ẹ̀dá wo tilẹ̀ ni tèmi yìí! Ta ni yóo gbà mí lọ́wọ́ ara tí ó fẹ́ ṣekú pa mí yìí?
25 Háà! Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun! Òun nìkan ló lè gbà mí là nípa Jesu Kristi Oluwa wa.Bí ọ̀rọ̀ ara mi ti wá rí nìyí: ní ìdà kinni, mò ń tẹ̀lé ìlànà òfin Ọlọrun ninu àwọn èrò ọkàn mi: ní ìdà keji ẹ̀wẹ̀, èmi yìí kan náà, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara, mo tún ń tọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀.