33 Ọlà ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ Ọlọrun mà kúkú jinlẹ̀ pupọ o! Àwámárìídìí ni ìdájọ́ rẹ̀. Iṣẹ́ rẹ̀ tayọ ohun tí ẹ̀dá lè tú wò.
34 Ìwé Mímọ́ sọ báyìí pé:“Ta ni mọ inú Ọlọrun?Ta ni olùbádámọ̀ràn rẹ̀?
35 Ta ni ó yá a ní ohunkohun rí tí ó níláti san án pada?”
36 Nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ohun gbogbo wà, láti ọwọ́ rẹ̀ ni ohun gbogbo ti ń wá, nítorí tirẹ̀ sì ni ohun gbogbo ṣe wà. Tirẹ̀ ni ògo títí ayérayé. Amin.