8 Ohun tí mò ń sọ ni pé Kristi ti di iranṣẹ fún àwọn tí ó kọlà, láti mú òtítọ́ Ọlọrun ṣẹ, kí ó lè mú àwọn ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba-ńlá ṣẹ,
9 ati láti jẹ́ kí àwọn tí kò kọlà lè yin Ọlọrun nítorí àánú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Nítorí èyí, n óo yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,n óo kọrin sí orúkọ rẹ.”
10 Ó tún sọ pé,“Ẹ bá àwọn eniyan rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè.”
11 Ó tún sọ pé,“Ẹ yin Oluwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdèkí gbogbo eniyan yìn ín.”
12 Aisaya tún sọ pé,“Gbòǹgbò kan yóo ti ìdílé Jese yọ,yóo yọ láti pàṣẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè,nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí àwọn orílẹ̀-èdè wà.”
13 Kí Ọlọrun tí ó ń fúnni ní ìrètí fi ayọ̀ tí ò kún ati alaafia fun yín nípa igbagbọ yín, kí ẹ lè máa dàgbà ninu ìrètí tí ẹ ní ninu Ẹ̀mí Mímọ́.
14 Ẹ̀yin ará, ó dá mi lójú pé ẹ̀yin fúnra yín kún fún inú rere, ẹ ní ìmọ̀ ohun gbogbo, ẹ mọ irú ìmọ̀ràn tí ẹ lè máa gba ara yín.