2 Ó pọ̀ pupọ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. Ekinni, àwọn Juu ni Ọlọrun fún ní ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀.
3 Ẹ lè wá sọ pé, “Anfaani wo ni ó wà ninu èyí nígbà tí àwọn mìíràn ninu wọn kò gbàgbọ́? Ǹjẹ́ aigbagbọ wọn kò sọ ìṣòtítọ́ Ọlọrun di òtúbáńtẹ́?”
4 Rárá o! Ọlọrun níláti jẹ́ olóòótọ́ bí gbogbo eniyan bá tilẹ̀ di onírọ́. Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Kí ìwọ Ọlọrun lè jẹ́ olódodo ninu ọ̀rọ̀ rẹ,kí o lè borí nígbà tí wọ́n bá pè ọ́ lẹ́jọ́.”
5 Bí aiṣododo wa bá mú kí òdodo Ọlọrun fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ni kí á wá wí? Ṣé Ọlọrun kò ṣe ẹ̀tọ́ láti bínú sí wa ni? (Mò ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé eniyan ni Ọlọrun.)
6 Rárá o! Bí Ọlọrun kò bá ní ẹ̀tọ́ láti bínú, báwo ni yóo ṣe wá ṣe ìdájọ́ aráyé?
7 Bí aiṣotitọ mi bá mú kí ògo òtítọ́ Ọlọrun túbọ̀ hàn, kí ni ṣe tí a tún fi ń dá mi lẹ́bi bí ẹlẹ́ṣẹ̀?
8 Ṣé, “Kí á kúkú máa ṣe ibi kí rere lè ti ibẹ̀ jáde?” Bí àwọn onísọkúsọ kan ti ń sọ pé à ń sọ. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yẹ fún ìdálẹ́bi.