Romu 4:11-17 BM

11 Ó gba àmì ìkọlà bí ẹ̀rí iṣẹ́ rere nípa igbagbọ tí ó ní nígbà tí kò ì tíì kọlà. Nítorí èyí, ó di baba fún gbogbo àwọn tí ó ní igbagbọ láì kọlà, kí Ọlọrun lè kà wọ́n sí ẹni rere;

12 ó sì di baba fún àwọn tí ó kọlà ṣugbọn tí wọn kò gbẹ́kẹ̀lé ilà tí wọ́n kọ, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní irú ọ̀nà igbagbọ tí baba wa Abrahamu ní kí ó tó kọlà.

13 Nítorí kì í ṣe nítorí pé Abrahamu pa Òfin mọ́ ni Ọlọrun fi ṣe ìlérí fún òun ati ìran rẹ̀ pé yóo jogún ayé; nítorí ó gba Ọlọrun gbọ́ ni, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere.

14 Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ń tẹ̀lé ètò Òfin ni yóo jogún ìlérí Ọlọrun, a jẹ́ pé ọ̀ràn àwọn tí ó dúró lórí igbagbọ di òfo, ìlérí Ọlọrun sì di òtúbáńtẹ́.

15 Nítorí òfin ni ó ń mú ibinu Ọlọrun wá. Ṣugbọn níbi tí kò bá sí òfin, kò sí ẹ̀ṣẹ̀.

16 Ìdí nìyí tí ìlérí náà fi jẹ́ ti igbagbọ, kí ó lè jẹ́ ọ̀fẹ́, kí ó sì lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún gbogbo ọmọ Abrahamu. Kì í ṣe fún àwọn tí ó gba ètò ti Òfin nìkan, bíkòṣe fún ẹni tí ó bá ní irú igbagbọ tí Abrahamu ẹni tí ó jẹ́ baba fún gbogbo wa ní.

17 Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Mo ti yàn ọ́ láti di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.” Níwájú Ọlọrun ni Abrahamu wà nígbà tí ó gba ìlérí yìí, níwájú Ọlọrun tí ó gbẹ́kẹ̀lé, Ọlọrun tí ó ń sọ òkú di alààyè, Ọlọrun tí ó ń pe àwọn ohun tí kò ì tíì sí jáde bí ẹni pé wọ́n wá.